Ọpọlọpọ dukia ṣegbe lasiko ija Yoruba ati Hausa ninu ọja Lafẹnwa

Gbenga Amos

Ọpọlọpọ ṣọọbu ati awọn nnkan mi-in lo jona nigba ti awọn ọdọ Hausa ati Yoruba kan kọju ija sira wọn ninu ọja Lafẹnwa, to wa niluu Abẹokuta, ipinnlẹ Ogun, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe ija ti ẹnikẹni ko ti i mọ ohun to fa a naa waye laarin ọkunrin Hausa kan ati Yoruba. Niṣe lawọn Hausa naa ro pe ọkan ninu wọn to n ja yii ti ku pẹlu bi ijamba to ni ṣe pọ. Wọn ko si beṣu bẹgba, niṣe ni wọn bẹrẹ ija pẹlu awọn ẹya Yoruba to wa nibẹ, ni ọrọ ba di bo o lọ o yago.

Ija naa bẹrẹ lati alẹ ọjọ Aje, wọn si ja a wọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ti ọpọlọpọ ṣọọbu atawọn ọja to wa ninu wọn ti jona gburugburu, ọpọ eeyan fara pa, dukia ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu si jona.

Ohun to mu ọrọ naa le gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe wi ni bi wọn ṣe tun ṣe Seriki Hausa ti wọn pe pe ko waa pari ija naa leṣe.

Ọsibitu ijọba apapọ, Federal Medical Centre, to wa niluu Abẹokuta ni wọn gbe ọkunrin naa lọ to ti n gba itọju gẹgẹ bi iweeroyin Daily Trust ṣe sọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni alaafia ti n jọba lawọn agbegbe tiṣẹlẹ naa ti waye.

O fi kun un pe ẹnikẹni ko ku ninu ijamba naa gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kiri. ‘‘A ti mu awọn kan lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn mi o fẹẹ maa sọ iye eeyan ta a ti mu.

Ija ṣẹlẹ laarin Yoruba ati Hausa, awọn kan ni wọn lọ sigboro ti wọn n gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri pe ọkunrin Hausa naa ti ku, leyii ti ko si ri bẹẹ. Ohun to fa wahala ree ti gbogbo nnkan fi daru.

‘‘Ṣugbọn ko soootọ ninu ariwo ti awọn kan n pa kiri pe eeyan ku ninu iṣẹlẹ naa.’’

 

Leave a Reply