Ọrẹ meji ṣe paṣipaarọ iyawo, wọn lawọn fi pari ija ni

Ba  a ba lowo, a le ya ẹnikeji ẹni, o si le jẹ aṣọ tabi mọto, ṣugbọn ko sẹni ti i yaayan niyawo tabi ọkọ rẹ nilẹ tiwa nibi o, afi lorilẹ-ede Kenya yii kan naa, nibi ti awọn ọrẹ meji ti wọn n ba ara wọn ja tẹlẹ ti pari ija tan, ti wọn si ṣe paṣipaarọ aya wọn.

Orukọ awọn ọkunrin naa ni Josh Oduor ati Sakis, agbegbe Busia, ni wọn n gbe ni Kenya. Ọrọ obinrin naa la gbọ pe o n daja silẹ laarin wọn tẹlẹ, nitori wọn ni Josh lo kọkọ n gbọ finrin-finri pe Sakis n ba iyawo oun sun, pe wọn n yan ara wọn lale gidi.

Ọkunrin naa ko kọkọ gbagbọ, ṣugbọn nigba ti awọn to n fun un lọwọ ko yee sọ bẹẹ lo bẹrẹ si i ṣọ iyawo rẹ naa. Ọjọ kan lo si lọ sile Sakis, nibẹ lo ti ba iyawo rẹ to n fọ abọ, to n tun gbogbo ile Sakis ṣe bii pe ile tiẹ gan-an lo wa.

Gẹgẹ bi tẹlifiṣan KDRTV to fi iroyin naa sita ṣe wi, wọn ni Josh beere lọwọ iyawo ẹ pe bawo lo ṣe jẹ to sọ ara ẹ di iyawo ile Sakis, obinrin naa ko si fi ọrọ sabẹ ahọn sọ rara, ọwọ kan lo jẹwọ fọkọ rẹ pe ololufẹ oun tuntun ree, oun ati Sakis ti gba lati di ọkọ atiyawo, ọrọ awọn ti kuro ni ti ale yiyan o.

Iyawo Sakis ti lọ sile awọn obi ẹ ni tiẹ,  ija loun ati ọkọ n ja lori ọrọ ale yiyan yii, n lo ba gba ile awọn obi rẹ lọ.

Nigba tọrọ waa ri bayii, niṣe ni Josh gba ile awọn obi iyawo Sakis lọ, o si ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fun un. O rọ obinrin naa pe ko jẹ kawọn naa fẹra awọn, ko jẹ oro to o da mi ni mo da ọ.

Iyawo Sakis naa ko janpata mọ, nigba to gbọ pe ọkọ oun ti fẹyawo ọrẹ ẹ, oun naa gba lẹsẹkẹsẹ ni.

Awọn meji yii naa ko fi ọrọ wọn bo, niṣe ni wọn kuku kọja si teṣan ọlọpaa, wọn ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn nibẹ, ati bawọn ṣe pinnu lati di tọkọ-taya.

Bẹẹ lo si ṣe ti awọn ọrẹ meji paarọ iyawo, ti wọn si ni bẹẹ lawọn yoo maa ṣe aye awọn lọ.

Leave a Reply