Ori ko akẹkọọ ile-ẹkọ awọn eleto ilera yọ lọwọ awọn ajinigbe l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti kede pe awọn ti ri akẹkọọ ile-ẹkọ eto ilera, Osun State College of Health Technology, Ileṣa, Rukayat Bayọnle, tawọn ajinigbe gbe logunjọ, oṣu yii, gba pada.

Rukayat la gbọ pe awọn ajinigbe ti wọn jẹ marun-un niye ya wọ inu ile to n gbe lagbegbe Olomilagbala, niluu Ileṣa, ni nnkan bii aago meji ataabọ ọsan, ti wọn si ji i gbe lọ sinu igbo.

Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe bi kọmiṣanna ọlọpaa, Ọlawale Ọlọkọde, ṣe gbọ lo ti ko awọn ọlọpaa lọ sibẹ, ti wọn si gbe ija lọọ ba awọn ajinigbe naa ninu igbo.

Laarin wakati mẹta ti awọn ọlọpaa atawọn ọlọdẹ ti bẹrẹ si i dọdẹ awọn ajinigbe yii la gbọ pe wọn ti ri Rukayat gba pada lalaafia.

Ọlọkọde waa rọ gbogbo awọn araalu lati di oju-lalakan-fi-i-ṣọri lasiko yii, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lati gbogun ti iwa ibajẹ nipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply