Ori oku keji ti Niyi ge lawọn ọlọpaa fi mu un l’Odogbolu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, ALAROYE mu iroyin ọkunrin kan ti wọn ni oun atiyawo ẹ hu ori oku l’Odogbolu wa, pẹlu awọn ọkunrin meji mi-in ti wọn jọ ṣiṣẹ naa. Lọsẹ yii, awọn mẹrẹẹrin ti ba ALAROYE sọrọ, eyi lohun ti Niyi Fọlọrunṣọ, iyawo ẹ, Rẹmilẹkun, Taiwo Ṣonubi (Babalawo) ati Muideen Talubi sọ nipa iṣẹlẹ to waye loṣu kẹsan-an, ọdun 2020 naa

Niyi Fọlọrunṣọ:

Ọmọ Odogbolu ni mi, Ikọsa-Okerimi laduugbo wa, iṣẹ birikila ni mo n ṣe, ṣugbọn mo maa n ba ẹni to ba nilo ori wa a. Ori keji ti mo hu lawọn ọlọpaa fi mu mi yii, mo ti hu saaree ti mo ti ge ori kan ri, wọn o ri mi mu nigba yẹn.

Ẹni ti mo ge ori ẹ ṣikeji yii, Eko lo n gbe, ibẹ naa lo ku si ki wọn too gbe oku ẹ wa sile, nitori ọmọ Odogbolu loun naa. Emi ni mo ba wọn sinku yẹn, emi ni mo gbẹlẹ ti mo ṣe gbogbo ohun to yẹ.

Nigba ti Taye Ṣonubi waa loun nilo ori eeyan, o loun maa fun mi lẹgbẹrun mẹẹẹdogun naira, babalawo loun, o fẹẹ lo o ni, mo waa lọọ ba a hu oku ti mo ba wọn sin. Ọjọ ọdun Ileya to kọja yii ni mo sin oku yẹn, (ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, mo waa lọọ hu u l’Ọjọruu kan ninu oṣu kẹsan-an to kọja yii.

Iyawo mi ko tẹle mi lọ sibi ti mo ti hu oku yẹn, ṣugbọn oun naa mọ nipa pe mo fẹẹ lọọ hu u ni saaree.

Rẹmilẹkun Fọlọrunṣọ(Iyawo Niyi)

Mi o mọ nnkan kan nipa ọrọ ori olori yii. Mo ṣẹṣẹ fẹ Niyi ni, diẹ lo fi le loṣu mẹta ti mo fẹ ẹ. Oyun ẹ to wa ninu mi bayii gan-an ko ti i pe oṣu mẹta. Nigba ti mo ṣẹṣẹ fẹ ẹ yẹn, mo maa n ri i to maa n jade pẹlu bọbọ kan ti wọn n pe ni Ijẹbu, babalawo dẹ ni Ijẹbu yẹn.

Nnkan bii aago mọkanla alẹ si mejila oru ni Ijẹbu maa n waa pe e, ti wọn aa jọ jade lọ. Mo pe Niyi gẹgẹ bii ọkọ mi, mo ni nibo loun ati Ijẹbu maa n lọ lalaalẹ. O fasiko kan purọ fun mi pe awọn maa n lọ sa iṣẹ kan ni, mo n wo o niran, mi o ba a ja.

Igba to ya, mi o le mu un mọra mọ, mo ni mi o mọ inu ẹ, nitori ko na tan fun mi. Bi Ijẹbu ṣe tun wa lọjọ kan niyẹn laago kan oru, to n beere Niyi. Mo purọ fun un pe o ti sun, o waa ni to ba ti ji ki n sọ fun un pe oun ti lọ si Igbodu. Ki i ṣe pe ọkọ mi ti sun, ṣugbọn mi o fẹ ko jade loru yẹn pẹlu Ijẹbu ni mo ṣe purọ fun un.

Ori eleyii to ni mo mọ si yii, mi o mọ nnkan kan nipa ẹ. Mi o mọ igba ti wọn n ba ara wọn sọrọ nipa ori ajiyọ (Ori oku eeyan) mi o tiẹ mọ pe ori eeyan ni wọn n pe ni ori ajiyọ, afigba ti mo jokoo sita tawọn ọlọpaa waa mu mi nibi ti mo ti n ṣerun lọwọ. Oru lo dẹ gbe baagi ori oku naa de, ko tiẹ gbe e wọle, emi gan-an ti sun, mi o ri i, mi o dẹ mọ nipa ẹ

Ọmọ Odogbolu lemi naa, Efiyan ni wọn n pe ọdọ wa, itan-agbọn.

Taiwo Ṣonubi (Babalawo to bẹ Niyi lori oku)

Oniṣegun ni mi, ọmọ Ikẹnnẹ ni mi.

Ojule kẹfa, Opopona Fọlaṣade, ni mo n gbe n’Ikẹnnẹ, ṣugbọn Oke-Magbọn ni mo ti n ṣiṣẹ iṣegun.

Mo n palẹmọ ile lọjọ kan ni mo ri iwe oogun kan ti wọn kọ ọ sinu ẹ pe ori ajiyọ wulo, mi o mọ pe ori eeyan ni wọn n pe bẹẹ. Mo ṣaa ni ki Niyi ba mi wa a, o waa ni ẹgbẹrun lọna ogun naira loun fẹẹ gba, mo waa ni ṣe o wọn to bẹẹ ni, pe ẹgbẹrun mẹẹẹdogun ni ma a san, mo dẹ fun un.

Nigba to gbe e de ti mo ri i pe ori eeyan ni, ẹru ba mi, mo ni ṣe pe ori eeyan ni wọn n pe ni ori ajiyọ, mo ni mi o le lo o, nitori ẹya ara eeyan ni, mi o dẹ fẹ nnkan to maa maa dẹruba mi. Mo waa gbe e lọ sẹkule ile mi, mo bo o mọlẹ bẹẹ ninu apo to wa ni.

Mo mọ pe mo ti ṣẹ, ṣugbọn mo bẹ ijọba ki wọn foriji mi.

Muyideen Talubi

Ọmọ Ipẹru lemi, Ṣafẹtẹdo laduugbo mi n’Ipẹru. Mi o mọ nipa ọrọ ori yii rara, iyawo mi lo pe mi pe ara oun o ya, o ni ki n ba oun ra agbo wa. Ile awọn Ẹgbọn Niyi dẹ niyawo mi yẹn n gbe, mo waa ba a ra agbo lọ sibẹ, mo fẹẹ maa lọ, iyawo mi ni ki n ma lọ, ki n sun ti oun, bi mo ṣe sun sile wọn niyẹn.

Igba to waa di laaarọ, ni nnkan bii aago meji oru, Ẹgbọn Niyi waa pe mi pe ki n ba awọn mu tọṣilaiti awọn wa, ki n dẹ ba awọn tan an si nnkan tawọn fẹẹ ṣe.

Bi mo ṣe tan ina si i ni wọn gbe ori oku jade, ẹru ba mi, ṣugbọn wọn ni ki n ma pariwo. Wọn ti hu oku yẹn jade tẹlẹ, wọn o waa riran ge ori ẹ ni wọn fi ni ki n ba awọn tanna si i. Nigba ti mo dẹ ba wọn tan an si i ti wọn ge e tan, mo lọọ sun pada ni temi. Bo ṣe jẹ niyẹn tawọn ọlọpaa fi pada waa mu mi pe mo mọ nipa ẹ’’

Ohun ti awọn ọlọpaa sọ nigba ti wọn fi atẹjade sita lori awọn eeyan yii ni pe gbogbo wọn ni wọn jẹwọ pe awọn mọ nipa ori oku ti wọn lọọ hu naa. Latigba tọwọ si ti ba wọn ni wọn ti ko wọn da satimọle, ni Eleweeran.

Ibẹ naa ni wọn ṣi wa lasiko ti a n ṣe akojọpọ iroyin yii, ṣugbọn wọn yoo foju ba kootu lẹyin iwadii awọn agbofinro gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ.

One thought on “Ori oku keji ti Niyi ge lawọn ọlọpaa fi mu un l’Odogbolu

  1. Gbogbo won pata niwon mo nipa ori oku ti won n ge, babalawo to loun o mo pe ori eeyan niwon npe ni ajiyo, iro lo npa
    Muydeen to ni egbon Niyi wa pe oun laago kan oru pe koun bawon tan toosi laiti si ibi tiwon ti wu oku eeyan lati riran ge ori e, iro loun naa npa
    Iyawo Niyi to ni oko oun maa njade loru ogonjo pelu babaalawo, kilode ti ko le figbe ta ki gbogbo awpn ara ile bawon dasi tabi ko lo fejo e sun awon ebi e pe, nkan ti oko oun se ni yii o, gbogbo won pata nk ki ijoba fi won ba ile ejo, ki won so lo jejo ni kootu
    Ewon gbere ni ki adajo fi gbogbo won si.

Leave a Reply