Faith Adebọla, Eko
Nitori ọmọ oṣu mẹẹẹdogun to fipa ṣe ‘kinni’ fun, ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki Ṣeun Aina, ẹni ọdun mejidinlogoji, lọọ fẹwọn ọdun mẹẹẹdọgbọn jura.
Ile-ẹjọ to n gbọ ẹjọ iwa ọdaran abẹle ati ẹsun akanṣe (Domesic Violence and Sexual Offences Court) to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lo gbe idajọ kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lori ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọdaran ọhun.
Bi Agbefọba, Peter Owolabani, ṣalaye ni kootu pe irọlẹ ọjọ kẹta, oṣu ki-in-ni, ọdun 2018, ni nnkan bii aago marun-un aabọ ọjọ naa ni Ṣeun yọ kẹlẹ lọ sibi ti ọmọ irinsẹ naa wa, ni Ojule karun-un, ọna Dominion Estate, niluu Ijede, lagbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko, lo ba ki ọmọ ọhun mọlẹ, ọ bọ pata ẹ, o si bẹrẹ si i ba a ṣere egele.
Ọmọ ọhun ki i ṣe ọmọ ẹ o, ọmọ alajọgbele wọn ni, wọn ni iya ọmọ naa ko si nile nigba tiṣẹlẹ naa fi waye, gẹrẹ ti iya ọmọbinrin naa jade ni jagunlabi ṣiṣẹ buruku yii.
Lasiko ti igbẹjọ fi n lọ lọwọ lori ẹjọ naa, ẹlẹrii mẹta ọtọọtọ, titi kan agbefọba, lo jẹrii ta ko afurasi ọdaran ọhun. Bakan naa si ni dokita to ṣayẹwo fun ọmọbinrin naa jẹrii pe ọmọ naa ko si lodidi mọ, o ni ayẹwo iṣegun fihan pe ẹnikan ti ṣe ọmọ ọhun baṣubaṣu.
Olujẹjọ naa pe ẹlẹrii kan, dokita kan ati oun funra ẹ, ṣugbọn adajọ ni ẹri wọn ko muna doko rara.
Adajọ Abiọla Ṣọladoye sọ pe gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ fihan kedere pe eeyankeeyan kan ni Ṣeun, ati pe ọdaran ni, o si jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an labẹ isọri kẹtadinlogoje iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Eko, eyi ti wọn ṣatunṣe si lọdun 2015.
O ni idajọ oun ni pe ki ọdaran naa lọ fẹwọn ọdun mẹẹẹdọgbọn jura pẹlu iṣẹ aṣekara, ko si saaye fun sisan owo itanran kankan.