Ọrọ apara ati ẹtan ni bawọn kan ṣe n sọ pe Naijiria ko le pin si wẹwẹ-Atiku Abubakar

Faith Adebọla

 Igbakeji aarẹ orileede wa tẹlẹ ri, Alaaji Atiku Abubakar, ti sọ pe ọrọ apara nla ati ẹtan ni bawọn kan ṣe n sọ pe Naijiria ko le pin si wẹwẹ, tabi pe dandan ni ki orileede naa wa lodidi, sibẹ to jẹ awọn nnkan to le fọ Naijiria yanga lo n ṣẹlẹ lojoojumọ, o ni ko si majiiki kan ninu iṣọkan orileede wa.

Atiku sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, l’Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ni gbọngan Shehu Musa Yar’Adua Center, nibi ti wọn ti n ko iwe tuntun kan jade bii ọmọ tuntun. Akọle iwe naa ni ‘Remaking Nigeria: Sixty Years, Sixty Voices,’ eyi ti Onkọwe Chido Onumah kọ nipa Naijiria.

Iwe naa ṣakojọpọ awọn ọkan-o-jọkan aboyun ọrọ ati ero aritọkasi tawọn eeyan nla nla ti sọ nipa Naijiria, latigba ti orileede naa ti gba ominira lọdun 1960, ati ojuutu si awọn iṣoro to n koju ilẹ wa.

Gẹgẹ bii alaga ayẹyẹ naa, Atiku ni o yẹ kawọn ọmọ Naijiria kẹkọọ arikọgbọn lara Aarẹ Mohammadu Buhari, to jẹ ero ati igbesẹ to n fa ipinya niṣakoso rẹ n gbe lọpọ igba.

“O maa n pa mi lẹrin-in nigba tawọn eeyan ba n sọ pe iṣọkan Naijiria ko le fọ, dandan ni ki Naijiria wa lodidi, o si maa wa bẹẹ ni, ta lo sọ fun wọn bẹẹ? Wọn n sọrọ iṣọkan, ṣugbọn wọn n huwa ipinya, iṣọkan waa di ahẹrẹpẹ.

Ko si nnkan kan ninu ajọṣepọ Naijiria to wa titi lae. Ẹnikan o le sọ pe ọran-anyan ni igbeyawo oun nigba ti ọrọ oun ati iyawo tabi ọkọ ẹ ko ba wọ mọ, to jẹ ojoojumọ ni wọn o gbọ ara wọn ye, igba wo nigbeyawo naa o ni i tuka.”

Lori iṣoro eto aabo to mẹhẹ, Atiku ni pẹlu bii nnkan ṣe n lọ yii, ko sigba tawọn janduku agbebọn ko ni i di ẹgbẹ tijọba fọwọ si, tawọn gan-an maa lorukọ lọdọ ijọba.

“Ta lo lero pe orileede wa le waa di ojuko ati ibuba fawọn ajinigbe atawọn janduku loriṣiiriṣii, debii pe wọn maa sọ iwakiwa wọn di okoowo nla mọ wa lọwọ, bo ṣe ri yii?

Ijọba ti faaye gba awọn eeyan-keeyan yii lati maa jaye ori wọn falala debii pe ko le ya ẹnikẹni lẹnu mọ ti wọn ba lawọn fẹẹ forukọ silẹ lọjọ ijọba (Corporate Affairs Commission) tabi lọdọ ajọ olokoowo ilẹ wa (Nigerian Stock Exchange).

Lọdun marun-un sẹyin, ko siṣoro lọna Abuja si Kaduna, ko si ogun nilẹ Ibo, ko si sẹni to ronu kan Amọtẹkun ki aabo le wa nilẹ Yoruba.”

Alaaji Abubakar ni awọn eeyan ilẹ Hausa naa jẹbi lori ọrọ yii, tori wọn o ṣakiyesi bawọn janduku ṣe rọ lọ sinu papa Sahara to wa lagbegbe wọn, latari adagun omi Chad to gbẹ.

Leave a Reply