Ọsẹ kan lẹyin to wọle ibo, Aarẹ orileede Chad ti ku o!

Faith Adebọla, Eko

Orileede Chad, ọkan ninu awọn orileede alaamulegbe Naijiria ti padanu aarẹ wọn, Ọgbẹni Idriss Deby. Ọkunrin naa la gbọ pe o dagbere faye lowurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lẹni ọdun mejidinlaaadọrin (68), ọdun mọkanlelọgbọn lo si fi ṣolori ilẹ naa.

Olori ileeṣẹ ologun ilẹ naa, Ọgagun Bermandoa Agouna, sọ ninu atẹjade kan to fi lede nipa iṣẹlẹ naa pe bi Aarẹ Deby ṣe fara gbọgbẹ yannayanna loju ija nigba to ṣaaju awọn ọmọ-ogun ilu rẹ lọọ ba awọn ti wọn n halẹ mọ ijọba rẹ ja laipẹ yii lo papa yọri si iku fun un.

Ọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni wọn kede Ọgbẹni Deby gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu ibo apapọ ti wọn ṣẹṣẹ di lorileede ọhun, eyi ni yoo si jẹ saa kẹfa ti ọkunrin naa yoo dibo wọle sipo aarẹ, lati ọdun 1990 to ti gori aleefa.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni aarẹ yii ṣaaju ikọ awọn ọmọ ogun rẹ lọọ gbena woju awọn afẹmiṣofo Boko Haram ti wọn n da apa kan orileede Chad laamu, wọn si pa pupọ lara wọn, wọn le wọn jinna lagbegbe orileede wọn.

Leave a Reply