Igbimọ olugbẹjọ da ẹjọ Jẹgẹdẹ nu, wọn l’Akeredolu lo yege

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbimọ to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ti da ẹjọ ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, pe ta ko Gomina Rotimi Akeredolu to dije labẹ asia ẹgbẹ APC nu bii omi isanwọ.

Alaga igbimọ ọhun, Onidaajọ Umar Abubakar, lo ka idajọ naa ninu ijokoo wọn to waye niluu Akurẹ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Onidaajọ Umar ni ẹjọ ti Jẹgẹdẹ pe ko lẹsẹ nilẹ rara, bẹẹ ni ki i ṣohun ti igbimọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo lẹtọọ ati jokoo le lori nitori pe aarin ẹgbẹ oṣelu to fa oludije kalẹ ni kinni naa wa.

Leave a Reply