Ounjẹ aarọ l’Ọlọrunwa n lọọ ra ti ibọn awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fi pa a n’Ileṣa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọdekunrin kan ti gbogbo eeyan n pe ni Ọlọrunwa ni ọta ibọn ba lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun doju ija kọra wọn laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lagbegbe Irojo, niluu Ileṣa.

Ounjẹ aarọ la gbọ pe Ọlọrunwa lọọ ra ti ọta ibọn fi ba a, loju-ẹsẹ lo si jade laye lai de ileewosan rara.

Lati irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ laduugbo Irojo ti bẹrẹ si i doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ Aye ni Iwara, ti wọn si tun bẹrẹ wahala naa laago mẹsan-an aarọ Ọjọruu.

Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ ti aarọ Wẹsidee ṣoju ẹ, Adebayọ, ṣe ṣalaye, o ni ileeṣẹ pako kan, Sawmill, to wa lagbegbe Irojo, ni Ọlọrunwa ti n ṣiṣẹ, lẹyin to de ṣọọbu to fẹẹ lọọ ra ounjẹ aarọ lo ṣagbako ibọn awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa.

Arojo ti Irojo, Oluṣẹgun Akẹju, sọ pe oun pe awọn ọlọpaa ni kete ti oun gbọ iro ibọn laaarọ yii, o si rọ awọn araalu lati ṣe ṣuuru lori iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply