Ọwọ ajọ to n gbogun ti lilo ọmọ nilokulo tẹ obinrin meji l’Ekiti, ọmọ oṣu mẹta ni wọn ra ni miliọnu meji

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ajọ to n gbogun ti rira atililo ọmọ kekere nilokulo, NAPTIP, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, ti mu awọn obinrin meji kan, Ifeoma Ejide ati Funmilayọ Ibitoye, lórí ẹsun rira ati tita ọmọ oṣu mẹta ni miliọnu meji Naira, ni Ilupeju-Ekiti, ìjọba ibilẹ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti.

Ọga agba ileeṣẹ naa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Samson Ọladimeji, ṣalaye pe aṣiri awọn ọdaran meji ọhun tu lẹyin ti ọga agba kan lati olu ileeṣẹ naa to wa l’Abuja, Ọgbẹni Emuze John, ṣaaju ìkọ kan wa si ipinlẹ naa lati waa mu awọn afurasi ọdaran obinrin meji ọhun lẹyin ti wọn tawọn araalu ta wọn lolobo pe wọn ra ọmọ oṣu mẹta ni miliọnu meji Naira.

Ọga agba naa yii ṣalaye pe ọkan lara awọn ọdaran naa, Ifeoma Ejide, lo ta ọmọbinrin kan ti ko ti i ju oṣun mẹta lọ fun Arabinrin Funmilayọ Ibitoye, tiyẹn si ra ọmọ naa ni miliọnu meji Naira.

Gẹgẹ bi ọga agba NAPTIP naa ṣe sọ, “Awọn ẹlẹgbẹ mi to wa lati Abuja  ni wọn mu ọrọ naa wa pe obinrin kan nileeṣẹ ti wọn ti n bimọ, ti wọn si n ta ọmọ (baby factory), si ilu Ọwọ, nipinlẹ  Ondo, to si n ṣe kara-kata owo ọmọ keekeeke. Bakan naa ni awọn yooku rẹ wa nipinlẹ Ekiti.

O fi kun un pe obinrin to ra ọmọ naa ṣalaye pe ilu oyinbo ni ọkọ oun wa. Bo tilẹ jẹ pe miliọnu meji Naira lo ra ọmọ yii, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N700,000) lo san lara owo ọhun

Wọn ni awọn ọdaran mejeeji ti jẹwọ pe loootọ lawọn kopa ninu kara-kata ọmọ oṣu mẹta naa, ati pe awọn mejeeji ti wa latimọle, ti wọn si n gba oun silẹ lẹnu wọn.

Ọladimeji ni, “Ọrọ kara-kata ọmọ tuntun jojolo ti waa wọpọ bayii laarin awọn eeyan ipinlẹ Ekiti, atawọn ipinlẹ mi-in nilẹ Yoruba. Eyi to wọpọ ju ni bi awọn to n ṣe owo naa ṣe maa n loogun lati sọ eni ti wọn ba fẹẹ ra ọmọ lọwọ rẹ di dindinrin, ti tọhun ko si ni i mọ ohun to n ṣe mọ lakooko ti wọn ba fẹẹ ra ọmọ naa.”

Nigba ti awọn akọroyin n fi ọrọ wa a lẹnu wo, Arabinrin Ifeoma to ta ọmọ naa, sọ pe oun jẹ ẹni to maa n tọju alaboyun ati okunrin ti nnkan ọmọkunrin rẹ ko ba ṣiṣẹ daadaa. Nigba ti wọn beere boya o maa n ta ọmọ, ọmọdebinrin yii sọ pe oun kọ ni oun ta ọmọ oṣu mẹta naa.

Bakan naa, Arabinrin Funmilayo Ibitoye, sọ pe oun ko ra ọmọ lọwọ afurasi naa, o ni niṣe loun bimọ oun sọdọ obinrin ti wọn sọ pe oun ra ọmọ lọwọ rẹ yii niluu Ọwọ, ati pe obinrin yii lo tọju oun nigba ti oun wa ninu oyun, titi di akoko ti oun fi bimọ naa.

O ṣalaye pe lẹyin ti oun ṣegbeyawo tan, ọdun mẹẹẹdọgbọn loun fi duro ki oun too ri ọmọ bi.

 

Leave a Reply