Shina Peller fi ẹgbẹ Akọọdu silẹ, o ba PDP lọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Aṣofin to n ṣoju agbegbe Iṣẹyin nileegbimọ aṣoju-ṣofin orileede yii tẹlẹ, Ọnarebu Shina Peller, ti fi ẹgbẹ oṣelu Accord Party silẹ, o lẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) loun n ṣe bayii.

Peller, ẹni to ṣoju ẹkun idibo to ko ijọba ibilẹ Isẹyin/Itẹsiwaju  ati Kajọla sinu nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ yii tẹlẹ, lo lewaju awọn bii ẹgbẹrun meji (2000), eeyan ti wọn ti inu ẹgbẹ oṣelu Akọọdu ya lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP bayii.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo tẹwọ gba wọn sinu ẹgbẹ Alaburada nibi ariya nla kan to waye niluu Isẹyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu Kejì, ọdun yii.

Nigba to n ki wọn kaabo sinu ẹgbẹ PDP, nibi ariya ti wọn fi gba wọn wọnu ẹgbẹ ọhun, Gomina Makinde, ẹni ti Amofin Adebayọ Lawal ti i ṣe igbakejirẹ ṣoju fun fi da awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun naa loju pe gbogbo anfaani ti awọn to ti wa ninu ẹgbẹ tipẹ ni lawọn paapaa yoo maa lẹtọọ si.

Ninu ọrọ akọsọ ẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Peller, sọ pe nitori iṣẹ ribiribi ti ijọba PDP n ṣe nipinlẹ naa labẹ iṣakoso Gomina Makinde, lo jẹ ki awọn pinnu lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ni Peller latilẹ, orukọ ẹgbẹ ọhún lo fi dibo wọle igbimọ aṣoju-ṣofin. O dupo aṣofin agba kin-in-ni, fun ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ, ninu iidibo ọdun 2023 to kọja, ṣugbọn o fìdi-rẹmi sọwọ Sẹnetọ Fatai Buhari, ẹni to wa nipo naa, to si tun ipo ọhun di, to si pada wọle fun saa kẹta nipo ọhun.

Ibinu iṣẹlẹ yii lo mu ki Ọnarebu Peller kuro ninu ẹgbẹ APC, to si darapọ mọ ẹgbẹ Akọọdu, to tun ti pada fi silẹ yii.

 

Leave a Reply