Owo Akeredolu da wahala silẹ laarin awọn to fẹẹ dibo l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade,Akurẹ

Awọn ẹgbẹ kan ko ara wọn jọ, wọn ni awọn fẹẹ dibo idaranwo fawọn ẹgbẹ oṣelu to wa ni ipinlẹ Ondo, ki awọn le mọ ẹgbẹ ati ẹni ti awọn yoo ṣe atilẹyin fun lasiko ibo gomina to n bọ yii, ẹgbẹ Coalition 2020 ni wọn pe ara wọn.  Ṣugbọn ija buruku ṣẹlẹ nibi idanrawo eto idibo naa lọsan-an ana, ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii, nigba ti wọn bẹrẹ si i fi ẹsun pe awọn kan ti gba owo abẹtẹlẹ lọwọ Arakunrin Rotimi akeredolu kan ara wọn.

Ohun gbogbo kọkọ n lọ letoleto nigba ti wọn bẹrẹ eto ọhun nile-itura nla kan to wa lagbegbe Ijapọ, Akurẹ lọsan-an ọjọ naa ṣugbọn lojiji ni nnkan deedee yi biri, tawọn ọmọ ẹgbẹ naa si doju ija kọ ara wọn.

Ọnarebu Akin Akinbọbọla to jẹ alaga gbogbogboo fun ẹgbẹ Coalition sọ ninu ọrọ akọsọ rẹ pe inu oṣu kẹfa ọdun to kọja lawọn ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ naa pẹlu eeyan mẹrindinlogun pere ti awọn jọ bẹrẹ rẹ.

O ni awọn ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu kan bẹẹ ni ko si eyi ti awọn yan laayo ninu awọn oloṣelu to fẹẹ dije ninu eto idibo gomina to n bọ lọna nipinlẹ Ondo.

Akinbọbọla ni lati bi osu diẹ sẹyin lawọn ẹgbẹ oṣelu bii ADC, APC, PDP ati ZLP ti n wa sọdọ awọn fun siṣe atilẹyin fun wọn ki wọn le rọwọ mu ninu eto idibo naa. O ni idi ree ti awọn fi pejọ lọjọ naa ki awọn le dibo laarin ara wọn lori eyi to yẹ ki awọn ṣatilẹyin fun ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mẹrẹẹrin.

Bo ṣe sọrọ yii tan ni wọn bẹrẹ eto idibo loootọ, lẹyin ti wọn pari eto idibo ti wọn si n ka a lọwọ ni ija bẹ silẹ laarin wọn. Ẹnikan to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ZLP lo kọkọ dide to si ni oun fẹẹ mọ iye awọn to lẹtọọ ati dibo ki wọn le mọ iye ibo ti yoo jẹ itẹwọgba nigba ti wọn ba ka ibo tan.

Eyi lo ṣokunfa bi atọkun eto naa ṣe da ẹnu duro diẹ na pẹlu ibo to n ka lọwọ to si sare ka iye awọn ti wọn gba laaye lati dibo nijọba ibilẹ ati inu ẹgbẹ kọọkan eyi ti ko fi bẹẹ tẹ ọkunrin naa lọrun. Nigba to si sare dide nibi to jokoo si lati lọọ fẹhonu rẹ han nibi ti wọn ti n ka ibo lọwọ, awọn ẹsọ alaabo ni wọn pade rẹ lọna ti wọn si fipa wọ ọ jade kuro ninu gbọngan ti wọn ti n ṣeto ọhun.

Bo tun ṣe ku diẹ ki wọn pari ibo kika lọmọ ẹgbẹ ZLP mi-in, Ọnarebu Bamiduro Dada, to jẹ ọkan pataki ninu awọn alatilẹyin igbakeji gomina ipinlẹ Ondo tun binu dide to si fẹẹ lọọ ja apoti ibo gba lọwọ awọn to n ṣeto naa. Kiakia lọrọ ti di ariwo ati ijakadi nla, ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa atawọn ẹsọ alaabo mi-in ti wọn wa nibi isẹlẹ ọhun ni wọn fi tete ri ọrọ naa yanju diẹ.

Ninu ọrọ ti agba oloṣelu ọhun ba awọn oniroyin sọ ko too di pawọn ọlọpaa gbe e lọ si agọ wọn lo ti fẹsun kan awọn oludari eto naa pe isẹ miliọnu mẹwaa Naira ti wọn gba lọwọ ẹgbẹ APC lalẹ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni wọn n jẹ, o ni ilana ti wọn fi ṣeto naa lodi patapata si ohun ti awọn jọ fẹnuko le lori.

Ẹgbẹ APC lo pada jawe olubori pẹlu ibo mejilelọgọjọ ti wọn ni, ẹgbẹ ZLP to ni ibo mọkandinlaaadọrun-un lo ṣe ipo keji, Ẹgbẹ PDP gba ipo kẹta pẹlu ibo mẹtadinlaaadọrin ti ẹgbẹ ADC si ni ibo mẹfa pere.

Eyi naa lo sokunfa bi Akinbọbọla ṣe kede loju gbogbo awọn to wa ninu gbọngan ọhun pe oludije ẹgbẹ APC, Gomina Rotimi Akeredolu, lawon yoo ṣe atilẹyin fun ninu eto idibo naa.

Lori ọrọ owo abẹtẹlẹ ti wọn lo gba lọwọ ẹgbẹ to jawe olubori, iyẹn ẹgbe Akeredolu, alaga ọhun sẹ kanlẹ lori ẹsun naa, o ni gbogbo awọn aṣoju bii irinwo ti wọn kopa ninu eto idibo naa ni wọn le jẹrii si i pe ko si eru ninu ohun gbogbo ti awọn ṣe.

Leave a Reply