Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori ti wọn n fi aworan alaworan lù awọn eeyan ni jibiti, gende ọkunrin mẹta ti dero ahamọ ọgba ẹwọn bayii.
Ajọ to n gbogun ti jibiti owo ati iwa magomago, EFCC, ẹka tipinlẹ Ọyọ to wa nIbadan lo mu wọn. Orukọ wọn ni Samuel Tanimoowo Owolabi (Keilah Forgey), Akinrimade Adepoju Sunday pẹlu Azeez Yussuf Akinkunmi.
Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa n’Ibadan ati tipinlẹ Ọyọ, ni wọn ti da awọn ipanle ọmọ yii lẹbi ẹsun jibiti.
Onidaajọ Patricia Ajoku ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, lo ṣedajọ Samuel Owolabi ati Akinrimade Adepọju, to si ju wọn sẹwọn nitori ẹsun fifi aworan alaworan lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara ati ṣiṣe gbaju-ẹ, eyi to lodi sofin orileede yii to ṣe e leewọ fun ẹnikẹni lati lu eeyan ni jibiti, paapaa lori ẹrọ ayelujara.
Ẹwọn ọdun kan atoṣu meje lo sọ Owolabi si, nigba to paṣẹ pe ki Akinrinmade lọọ fẹwọn oṣu mẹta pere jura ni tiẹ.
Lẹyin eyi nile-ẹjọ gbẹsẹ le awọn ohun ini
bii ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Lexus ti nọmba ẹ jẹ RX300 SUV, Toyota Lexus RX330 SUV, ẹrọ agbeletan, aago ọwọ olowo iyebiye, ẹrọ amohunmaworan, ẹrọ ibanisọrọ atawọn nnkan mi-in t’Owolabi fọna eru ko jọ.
Akinrinmade ni tiẹ nijoba gbẹsẹ le owo to to milionu kan naira ti wọn ba ninu asunwọn ile ifowopamọ ẹ pẹlu ẹrọ ibanisọrọ Iphone 11.
Eni kẹta, Azeez Yusuf, l’Onidajọ Bayọ Taiwo tile-ẹjọ giga tipinlẹ Ọyọ ni ko lo oṣu mẹta ni gbaga nitori to lù ọkunrin kan ti wọn npe ni Mike Aderson ni jibiti.
Lẹyin naa nile-ẹjọ ni ko da aadọfa (N110) owo dọla pada fun ọkunrin to lu ni jibiti naa.