Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Diẹ lo ku kawọn ọdọ tinu n bi dana sun afurasi ajinigbe kan to n dibọn bii were niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lopin ọsẹ to kọja.
Afurasi ọhun, Labram Ibrahim, lawọn eeyan ṣakiyesi pe o mura bii were, to si n rin regberegbe kiri agbegbe gereeji Akurẹ si Itanla, niluu Ondo.
Awọn eeyan ko kọkọ fi bẹẹ ka irin to n rin kiri si babara, ṣugbọn nigba ti wọn ri ọkunrin Fulani ọhun lojiji to fẹẹ wọnu ọkọ jiipu dudu kan to paaki mọ ọn lẹgbẹẹ nibi to ti n rin kiri ni wọn sare si i, ti Ọlọrun si jẹ ki wọn ri i mu.
Wọn kọkọ lu u bii ẹgusi baara na, awọn ẹsọ Amọtẹkun to de sibi iṣẹlẹ ọhun lasiko ni wọn gba a silẹ lọwọ wọn, ti wọn ko fi dana sun un lọjọ naa.
Nigba ti wọn n fọrọ wa afurasi ọhun lẹnu wo, lara alaye to ṣe fawọn eeyan ni pe ilu Sokoto loun ti wa, o ni ọga oun kan ti oun mọ si Rabiu lo mu oun lọ si ibuduko ti wọn ti n wọ mọto l’Akurẹẹ pe ki oun maa bọ l’Ondo.
O ni funra ọga oun lo san ẹẹdẹgbẹrin Naira gẹgẹ bii owo ọkọ, to si tun fun oun ni ẹgbẹrun kan aabọ Naira to wa lapo oun lasiko ti wọn mu oun.
Fulani ọga rẹ yii lo ni wọn fi jẹ olori awọn Fulani Popoọla, lagbegbe Ayedun, Akurẹ.
Ọkunrin ọhun ni ki awọn too kuro l’Akurẹ ni Rabiu ti pasẹ fun oun lati yọ siimu inu foonu oun danu ko too fi oun le ọkọ to n bọ l’Ondo lai sọ pato iṣẹ ti oun fẹẹ waa ṣe fun oun.
O ni gbogbo bi oun ti n rin kiri naa ni Rabiu atawọn Fulani mẹta mi-in ti wọn jọ wa ninu ọkọ n tẹle oun, ti wọn si n sọ oun lọwọ lẹsẹ.
Ibrahim ni loootọ loun mura bii were, bo tilẹ jẹ pe ko si aisan kankan to n ṣe oun, o ni bi oun ṣe mura lo fu awọn eeyan kan lara ti wọn fi mu oun lasiko ti oun fẹẹ tẹsiwaju lati maa lọ siluu Ọrẹ gẹgẹ bii aṣẹ ti Rabiu pa foun.
ALAROYE gbọ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ pe awọn ẹsọ Amọtẹkun ti n gbe igbesẹ ati fi pampẹ ofin gbe Rabiu to daruko fun wọn pẹlu awọn Fulani mẹtẹẹta ti wọn jọ wa ninu ọkọ fun ifọrọwanilẹnuwo.