Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ awọn Fulani to n gbe ibọn da ẹran l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ awọn ẹsọ Amọtẹkun ẹka ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn Fulani darandaran mẹta pẹlu awọn nnkan ija oloro tí wọn n gbe rin lasiko ti wọn n daran.

Awọn mẹtẹẹta ọhun la gbọ pe wọn fi pampẹ ọba gbe ninu igbo ọba lẹyin ti Gomina Rotimi Akeredolu ti pasẹ pe kawọn to ba n ṣamulo igbo ọba lọna aitọ tete kuro laarin ọjọ meje pere.

Awọn Fulani ọhun ni wọn foju bale-ẹjọ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lori ẹsun, gbigbimọ-pọ huwa to lodi sofin, biba awọn nnkan ija oloro ni ikawọ wọn ati wiwọ inu igbo ọba lọna aitọ.

Onidaajọ Daramọla Ṣekoni ni ki wọn lọọ fawọn olujẹjọ mẹtẹẹta pamọ sọgba ẹwọn lẹyin ti wọn ba ti ṣayẹwo arun Korona fun wọn, ti wọn si ri i daju pe ko si aisan náà lara wọn.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2021, ladajọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply