Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ba ọmọ to parọ pe wọn ji oun gbe nitori ko le gbowo lọwọ awọn obi ẹ

Monisọla Saka

Niṣe ni ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) kan, Ṣẹgun Mafimidowo, n ka boroboro l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2022 taa wa yii, pe niṣe loun parọ pe awọn ajinigbe ji oun gbe pamọ koun baa le rowo gba lọwọ awọn obi oun.

Lasiko ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ẹka to n ri si iwadii iwa ọdaran lagbegbe Eleweeran, l’Abẹokuta, n ṣafihan awọn afurasi ọdaran ni Mafimidowo lo sọ eleyii.

O ni niṣe loun lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọrẹ oun kan, tawọn si beere owo to to miliọnu mẹjọ Naira lọwọ awọn obi oun lẹyin to sọ fun wọn pe awọn agbebọn kan ti ji oun gbe lagbegbe Ṣagamu nipinlẹ Ogun.

Lasiko ti wọn n fi oju awọn ọdaran ọhun han’de, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe Mafimidowo tun fi fọto ibi ti wọn ti de ọwọ ati ẹsẹ ẹ ranṣẹ si awọn obi ẹ ki wọn le tete yara ṣa owo jọ lati gba a silẹ.

“Awọn ajinigbe ofege yii pada waa fi nọmba akaunti kan to jẹ ti ẹni kan to n jẹ Ogbu Abraham ti wọn yoo sanwo si ṣọwọ si awọn obi Ṣẹgun. Ṣugbọn awọn ikọ to n gbogun ti iwa ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun bẹrẹ iṣẹ iwadii labẹnu, ninu iwadii yii si ni aṣiri ibi ti Mafimidowo atawọn to ni wọn ji oun gbe ọhun farapamọ si”.

Nigba to n sọrọ lasiko ti wọn ṣafihan awọn ọdaran ọhun, Mafimidowo ni, “Nitori ki n le ri owo gba lọwọ awọn obi mi ni mo ṣe parọ pe wọn ji mi gbe.

” Awọn ọrẹ mi ti mo wa iranlọwọ lọ sọdọ wọn ni wọn gba lati ba mi ṣe bii awọn ajinigbe, ki n le rowo gba. Ni bayii, mo ti kabaamọ ohun ti mo ṣe”.

Lara awọn afurasi ọdaran mi-in tawọn agbofinro ṣafihan wọn ni awọn oniṣẹ ibi atawọn arufin loriṣiiriṣii bii awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, awọn ẹsun bii ifipabanilopọ, ipaniyan, ijinigbe atawọn mi-in.

Oyeyẹmi ṣalaye pe ọwọ awọn agbofinro tẹ awọn ọdaran yii lawọn oriṣiiriṣii ilu bii Abẹokuta, Ṣagamu ati apa Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, fun oriṣiiriṣii iwa laabi bii ipaniyan, ijinigbe, ifipabanilopọ, ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun atawọn iwa ibi mi-in.

O sọ ọ di mimọ pe ọwọ awọn eeyan oun ba to afurasi ọdaran bii mejilelogoji (42) laarin inu oṣu Kẹrin si oṣu Kẹfa, ọdun yii, pẹlu oriṣiiriṣii awọn ẹru ofin bii awọn ibọn ibilẹ, ọta ibọn, ada mẹrin, sisọọsi ati aake.

Oyeyẹmi ni gbigbe tawọn fi ofin gbe awọn ọdaran naa jẹ ara akitiyan ileeṣẹ awọn lati mu adinku ba ọrọ ẹgbẹ okunkun atawọn iwa laabi mi-in kaakiri ipinlẹ naa, paapaa ju lọ ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kaakiri ipinlẹ Ogun.

Leave a Reply