Ọwọ ọlọpaa tẹ Lawrence to fipa ba abirun sun lẹyin mọṣalaaṣi l’Oṣogbo

Florence Babasola, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan, Akinọla Lawrence Adetayọ, ẹni ogoji ọdun, lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun pe o fipa ba ọmọbinrin abirun kan lo pọ lọna to mu ifura dani.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye fun ALAROYE, aago meje aabọ alẹ ọjọ karun-un, oṣu kọkanla, ọdun yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ọpalọla ni ṣe ni iya ọmọbinrin naa, Abọlarinwa Rẹmilẹkun, ran ọmọ rẹ torukọ rẹ n jẹ Kafayat lati ra nnkan wa nitosi ile wọn to wa laduugbo Ataọja, niluu Oṣogbo.

Bo ṣe n lọ ni Lawrence dena de e, o si fi agidi wọ ọ lọ sẹyin mọṣalaṣi kan laduugbo naa, nibẹ lo ti tẹ aṣọ pupa silẹ, to si ba a lo pọ.

O ni nigba ti ọmọ yii, ẹni ọdun mẹrindinlogun, dele ni iya rẹ ṣakiyesi bo ṣe n ṣe, nigba ti wọn si tẹ ẹ ninu daadaa, o ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ, iya rẹ si lọọ fi to awọn ọlọpaa ibẹ leti.

Kia lọwọ tẹ Lawrence, o si ti wa ni ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran niluu Oṣogbo. Ọpalọla si sọ pẹlu idaniloju pe laipẹ ni yoo foji bale-ẹjọ.

One thought on “Ọwọ ọlọpaa tẹ Lawrence to fipa ba abirun sun lẹyin mọṣalaaṣi l’Oṣogbo

Leave a Reply