Gbenga Amos, Abẹokuta
Bo tilẹ jẹ pe ori ko afurasi ọdaran ti wọn porukọ ẹ ni Ṣakiru Famuyiwa yọ lọwọ iku ojiji, latari bi wọn ṣe fẹẹ fibinu dana sun un laaye, kawọn ọlọpaa too de, sibẹ, oun lo maa mọ ibi ti ara oun ku si pẹlu ajẹdaku iya ti wọn fi jẹ ẹ nigba tọwọ ba a nibi ti wọn loun ati ọrẹ ẹ ti fẹẹ ji ọmọ meji gbe ninu ṣọọṣi Sẹlẹ kan l’Abẹokuta.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin yii, niṣẹlẹ ọhun waye, ọjọ ti ọpọ awọn ẹlẹsin Kristẹni n ṣe ayẹyẹ ọdun Ajinde lọwọ ni, tọmọ-tọmọ bii akara si lawọn ṣọọṣi kun fọfọ lọjọ naa tori ayajọ ọjọ ti Jesu Olugbala ku ni.
Wọn ni bi eto isin ṣe n lọ lọwọ ni ṣọọṣi Sẹlẹ kan to wa lagbegbe Ijẹja, nitosi Ibara, niluu Abẹokuta, bẹẹ lafurasi ọdaran yii ati ọrẹ ẹ kan ba yọ kẹlẹ wọ ṣọọṣi naa, apa ibi ti wọn ko awọn ọmọde jọ si ni wọn lọ taara, ni wọn ba n jo, ti wọn si n ṣọdun pẹlu wọn.
Ko pẹ sasiko naa, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ASP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ ninu atẹjade to fi sọwọ s’ALAROYE lọjọ Satide pe awọn ọkunrin mejeeji fa ọmọ kọọkan dani, ọkan fa ọmọọdun mẹta, ekeji fa ọmọọdun meji aabọ, ni wọn ba rọra n jade lọ ni tiwọn.
Ọpẹlọpẹ ẹnikan to taju kan-an ri wọn lọọọkan, niyẹn ba figbe ta ni ṣọọṣi pe awọn ọkunrin meji ti n ko ọmọ meji lọ o, kia lawọn olujọsin da giiri tẹle wọn. Bi wọn ṣe ri i pe aṣiri ti tu, wọn fi awọn ọmọ meji naa silẹ, wọn gbe ere da si i, lawọn gende ninu ṣọọṣi naa ba gba fi ya wọn, awọn araalu si darapọ lati mu wọn.
Ṣakiru lọwọ ba, ekeji rẹ sa lọ raurau, ni wọn ba fi palaba iya jẹ ẹ. Nibi ti wọn ti n wa bẹntiroolu ati taya ti wọn maa fi sun un looyẹ lawọn ọlọpaa lati ẹka ileeṣẹ wọn to wa n’Ibara de, DPO wọn, CSP Nasirudeen Oyedele, lo ran wọn sibẹ tori awọn kan ti ta wọn lolobo ohun to ṣẹlẹ.
Ṣa, awọn ọlọpaa gba Ṣakiru lọwọ idajọ oju-ẹsẹ, wọn mu un lọ sahaamọ wọn. Ahamọ naa lo gba de ọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ to n ṣewadii iwa ijinigbe, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa, Lanre Bankọle, ṣe paṣẹ.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ, bẹẹ ni wọn ṣi n wa ekeji rẹ to na papa bora.