Ọwọ tẹ awọn marun-un pẹlu ọpọlọpọ apo igbo l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Awọn afurasi to n gbin igbo marun-un lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun oloro, ẹka tipinlẹ Ondo, tẹ lagbegbe Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lopin ọsẹ to kọja yii.

Awọn oniṣowo igbo ọhun, Alex Moses, ẹni ọdun marundinlogoji, Oshie Emmanuel, ẹni ogun ọdun, Friday Effiong, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Emmanuel Akpan, ẹni ọdun marundinlọgbọn ati David Friday, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun ni wọn mu pẹlu ọpọlọpọ oogun oloro ninu igbo nla kan ti wọn fara pamọ si lagbegbe Agọ Oyinbo, Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ọgbẹni Haruna Gagara to jẹ ọga agba patapata fun ajọ naa nipinlẹ Ondo pe lojiji lawọn lọọ ka awọn afurasi naa mọ inu oko ti wọn ti n ṣiṣẹ.

Ilẹ ibi ti wọn dako igbo si lo ni o to bii ọtalelugba din mẹwaa sarè (250 hectares of land) ninu igbo naa.

O ni ko tii pẹ rara tí awọn mu ọkọ nla kan to kun fọfọ fun igbo loju ọna marosẹ Ọgbẹṣẹ si Ọwọ.

Gagara ni awọn pada fidi rẹ mulẹ ninu iwadii awọn pe ipinlẹ Kano ni wọn n ko awọn ẹru to lodi sofin naa lọ.

Gbogbo awọn tọwọ tẹ naa lo ni wọn yoo foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply