Ọwọ tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n da wọn laamu ni Sagamu

Gbenga Amos, Abẹokuta
Mẹfa ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n da awọn eeyan ilu Sagamu ati agbegbe rẹ laamu tawọn ọlọpaa ti n wa nipinlẹ Ogun ti ko sọwọ wọn bayii, wọn si ti fọwọ ofin mu wọn.
Lara awọn ti ọwọ tẹ gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ ni Rafiu Oṣokọya, Azeez Abiọla, Ogunsanwo Waheed; Taoheed Ayọdele Kọlawọle, Adegbenro and Azeez Taiwo.
Awọn eeyan yii ni wọn ni wọn wa nidii bi wọn ṣe pa awọn mẹrin kan nipakupa nipinlẹ naa. O ni ọwọ tẹ awọn eeyan naa nigba ti olori ikọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun nipinlẹ naa, Shobiyi Oluwatosin, pe awọn pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n ṣepade oru lagbegbe Ayepe/Odogbolu.
Ipade ti wọn n ṣe naa la gbọ pe wọn ti n mura lati tun lọọ doju ija kọ awọn kan niluu naa.
Awọn eeyan naa ni wọn fa wahala, ti wọn si n da awọn araalu laamu.

Leave a Reply