Ọwọ tẹ awọn ọmọ Yahoo meji nibi ti wọn ti fẹẹ pe ori oku l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ palaba awọn ọmọ Yahoo meji kan lo ṣegi lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ wọn nibi ti wọn ti n gbiyanju ati pe ẹmi oku obinrin ojisẹ Ọlọrun kan jade ninu iboji rẹ l’Akurẹ.

Iranṣẹ Ọlọrun ọhun to jẹ oludasilẹ ijọ kan ti wọn porukọ rẹ ni House of Prayers and Praises for All Nations (Ile Adura ati Iyin fun gbobgo Orilẹ-ede), eyi to wa lagbegbe Sijuwade, l’Akurẹ, lo ti ku ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin, ti wọn si sinku rẹ sinu ọgba ṣọọsi rẹ ni kete lẹyin to ku.

 

 

Awọn ọdẹ ti wọn gba lati maa sọ inu ọgba ṣọọsi ọhun ni wọn ka awọn afurasi ọmọ Yahoo mejeeji mọ eti iboji

Nnkan bii aago kan oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn ọlọdẹ to n ṣọ inu ọgba ṣọọsi ọhun ka awọn afurasi ọmọ Yahoo mejeeji mọ eti iboji oloogbe ọhun ti wọn n pọfọ kikankikan lati pe ẹmi rẹ jade ninu iboji pẹlu erongba ati ba oku rẹ sun.

 

 

Ọkan ninu awọn ọmọ Yahoo ọhun lọwọ kọkọ tẹ, ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa teṣan Ala, niluu Akurẹ, lọwọ, lẹyin-o-rẹyin ni wọn ṣẹṣẹ ri ẹni keji rẹ mu nibi to lọọ farapamọ si.

Awọn afurasi mejeeji ni wọn ṣi wa nikaawọ awọn ọlọpaa, nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ.

Leave a Reply