Ọmọ ọdun mọkanla ni ọlọpaa yii fipa ba lo pọ niluu Ijagbo

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn gbe ọlọpaa kan, Monday Fọlọrunṣhọ, lọ, o si ti wa ninu ahaamọ bayii fun ẹsun pe o fipa ki ọmọ ọdun mọkanla kan mọlẹ niluu Ijagbo, nijọba ibilẹ Ọyun, nipinlẹ Kwara.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Ajayi Ọkasanmi, ṣalaye pe Fọlọrunṣhọ ni wọn lo tan ọmọde naa wọnu ọkan lara awọn yara to wa ni tesan ọlọpaa niluu Ijagbo, nibi to ti n ṣiṣẹ, to si ba a laṣepọ tipa.

Wọn ni lasiko to n ṣe kinni ọhun lọwọ lawọn ọdọ adugbo gba a mu, ti wọn si lu u daadaa.

Lẹyin ti wọn da sẹria fun un tan ni wọn ke pe awọn ọlọpaa lati waa gbe e lọ. Olu ileeṣẹ wọn to wa niluu Ilọrin ni wọn ru u lọ.

 

Leave a Reply