Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ajọ to n gbogun ti asilo oogun ati egbogi oloro ni ilẹ yii, (NDLEA), ti mu Sgt Ibrahim Musa to jẹ oṣiṣẹ ọmọ ologun tẹlẹ ri ati iyawo rẹ, Basirat Musa, pẹlu kokeeni giraamu mẹrin, igbo kilogram mejila le diẹ (12.133kg) ati oogun kan ti wọn n pe ni Flunitrazasepam giramu mẹẹẹdọgbọn (25), ni agbegbe Tankẹ Oke-Odo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe oṣiṣẹ ọmọ ologun ni Bareke ọmọ ogun to wa ni Abati, nipinlẹ Eko, ni Ibrahim Musa ko too di pe wọn gbe e lọ si 117 Battalion, niluu Chibok, nipinlẹ Borno, ko tọ pada fi iṣẹ ologun silẹ.
Ninu ọkọ ayọkẹlẹ (Honda Accord) ti nọmba rẹ jẹ : JJ 707BL Lagos, ti Basirat wa ni wọn ti ba awọn ẹru ofin ọhun, ti wọn si gba a mu nigba to fẹ gbe e fun onibaara wọn.
Nigba ti wọn n fi ọrọ wa ọkọ lẹnu wo, o ni ilu Chibok ni wọn ti fun oun ni ọwọ bi oun yoo ṣe maa gbe egboogi oloro naa, o ni lẹsẹkẹsẹ ti oun fi iṣẹ ologun silẹ loun ti yan egboogi oloro gbigbe laayo lati maa fi tọju mọlẹbi oun, iyawo meji, ọmọ mẹta ni awọn ẹbi to oun tọju.
O tẹsiwaju pe ilu Eko loun fi ṣe ibugbe bayii, ati pe oun ko sọ fun iyawo oun ti awọn jọ wa si Ilọrin pe ohun ti oun fẹẹ waa ṣe niyi. O ni ẹlẹẹkeji ree ti oun yoo gbe egboogi oloro wa si ilu Ilọrin.