Ọwọ tẹ Usman ni Sagamu, oun lo n ra kẹkẹ Maruwa tawọn ole ba ji l’Ekoo

Gbenga Amos, Ogun

 Yoruba bọ, wọn ni ‘agbepo-laja ko jale bii ẹni to gba a lọwọ ẹ’, owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta yii, Usman Abdullahi, tọwọ awọn ẹṣọ alaabo So Safe ba niluu Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii. Okoowo rira ati ṣiṣe ara-tun-ta kẹkẹ Maruwa tawọn ole ji gbe l’Ekoo lafurasi ọdaran naa n ṣe, tọwọ fi ba a.

Gẹgẹ bawọn So-Safe ṣe sọ, wọn ni oni-Maruwa kan, Ọgbẹni Kunle Ọdẹmọ, lo kegbajare wa sọfiisi awọn pe wọn ti ji kẹkẹ Maruwa oun lọ, ibi toun gbe e si ni wọn ti ji i, oun o si mọ ẹni to ṣiṣẹ buruku naa.

Eyi lo mu kawọn So-Safe lọọ mu irinṣẹ kan to n ba ẹrọ ayelujara ṣiṣẹ jade, irinṣẹ ti wọn fi n tọpasẹ nnkan irinna ti wọn ji gbe, tracker lawọn eleebo n pe e, irinṣẹ yii ni wọn lo ti wọn fi ri i pe ẹni to gbe kẹkẹ naa ko ti i gbe e jinna, agbegbe ilu Ṣagamu lo wa, ni wọn ba bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari ẹ.
Awọn ẹṣọ So-Safe lati Ijẹbu-Ode darapọ mọ ti Ṣagamu ati ti Rẹmọ, wọn n lo irinṣẹ naa, ẹrọ naa si n tọ wọn sọna titi to fi dari wọn si ile kan to wa laduugbo Sabo, niluu Ṣagamu, ibẹ ni wọn ti ri kẹkẹ Maruwa ọhun ti nọmba rẹ jẹ MEK-642-WV.

Wọn tun ba kẹkẹ Maruwa mi-in lẹgbẹẹ eyi ti wọn n wa, ko si nọmba lara ẹ, wọn si ri Usman Abdullahi to jẹwọ pe oun loun gbe awọn kẹkẹ ọhun sibẹ, o ni dukia oun ni.

Wọn beere lọwọ ẹ ibi to ti ri i, o ni niṣe loun ra wọn, tori okoowo ara-tun-ta kẹkẹ Maruwa loun n ṣe, o ni ọrẹ oun kan, Ugochukwu, lo maa n ta a foun, agbegbe Ṣẹlẹ, lọna Oṣodi si Mile 2, Apapa, nipinlẹ Eko, lọrẹ rẹ naa wa. O ni miliọnu meji o din ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (N1.9m) loun ra awọn kẹkẹ mejeeji ti wọn ba lọdọ oun naa.

Ṣa, wọn ti mu Usman lọ fun iwadii, lẹyin ti wọn si ti gba ọrọ silẹ lẹnu ẹ tan, wọn fa oun ati ẹru ole to loun ra l’Ekoo, le awọn ọlọpaa lọwọ lẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Igbeba, ki wọn le tubọ tuṣu desalẹ ikoko lori ọrọ yii. Lẹyin naa ni wọn yoo foju afurasi yii bale-ẹjọ.

Leave a Reply