Ọwọ ti ba ‘Stubborn’, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ilaro

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

O pẹ tawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti n wa Dare Ojugbele tawọn eeyan n pe ni ‘Stubborn’, n’Ilaro. Koda, orukọ ẹ ti wa ninu iwe awọn ọdaran tijọba n wa, ko too di pe o bọ sọwọ awọn agbofinro logunjọ, oṣu kẹjọ yii.

Ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ naa ni DPO Ilaro, CSP Ọlayẹmi Jacob, ẹni to n wọde pẹlu awọn ikọ rẹ lọna Idọgọ, ṣadeede ri Stubborn ti wọn ti n wa tipẹ lori ọkada, bi wọn ṣe da ọkada naa duro niyẹn.

Wọn yẹ ara ẹ wo loju-ẹsẹ, ibọn ilewọ kan lawọn ọlọpaa sọ pe awọn ri lapo ẹ pẹlu ọta ibọn ti wọn ko ti i yin, awọn nnkan ija mi-in pẹlu awọn oogun to fi n ṣagbara naa si tun wa lapo ẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Dare Ojugbele ti wọn ni agbegbe Itawaya, n’Ilaro, lo ti wa, jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ loun. Wọn lo jẹwọ pe gbogbo rogbodiyan ẹgbẹ okunkun to n waye n’Ilaro ati agbegbe rẹ ko ṣẹyin oun atawọn ẹgbẹ oun.

Nigba to n paṣẹ pe ki wọn gbe Stubborn lọ sẹka itọpinpin lọdọ awọn ọlọpaa, CP Edward Ajogun tun sọ pe aaye ṣi wa fun ọmọ ẹgbẹ okunkun yoowu to ba fẹẹ kọ ẹgbẹ naa silẹ lati wa bayii, nitori ijọba yoo ṣe aforiji fun wọn, wọn yoo sọ wọn di ọmọ gidi. Ṣugbọn ẹni to ba kọ lati ṣe bẹẹ yoo da ara rẹ lẹbi tọwọ ba pada tẹ ẹ, nitori tọhun yoo jiya bii ẹran oriso pẹlu ofin ni.

Leave a Reply