Owolabi ji mọto mama ẹ gbe, ibi to ti fẹẹ ta a ni wọn ti mu un

Faith Adebọla, Eko

Bi ki iba ṣe pe ẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko lọrọ naa ti jade ni, eeyan iba jiyan pe boya wọn purọ mọ ọdọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn yii, Samuẹl Owolabi,  ni. Ṣugbọn SP Benjamin Hundeyin lo sọ ọ di mimọ pe awọn ti mu ọmọkunrin yii, niṣe lo ji mọto mama ẹ gbe, o si wa ọkọ naa lọ sibi ti wọn ti n ta aloku mọto, o fẹẹ lu ọkọ naa ta ni gbanjo mọ’yaa ẹ nidii.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro naa fi soju opo ayelujara ikanni abẹyẹfo (tuita) rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ yii, Hundeyin ni:
“Ẹ wo Samuel Owolabi, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ta a ri mu l’Ekoo, nibi to gbe ọkọ ayọkẹlẹ mama ẹ lọ, to loun fẹẹ ta a, ti wọn si ti n yọwo ẹ. Nigba ta a pe mama naa lori aago pe ọkọ ẹ wa nibi bayii bayii, ko waa gbe e, niṣe lara ẹ ṣẹgiiri, o ya a lẹnu. Njẹ ọmọ rẹ ọkunrin tabi obinrin le ta dukia rẹ lai jẹ ko o mọ, to o si fọwọ si i? Njẹ o da ẹ loju pe ko le ṣẹlẹ si ẹ?”

A gbọ pe inu ọgba atọkọṣe kan lọdaju ọmọ yii wa ọkọ ayọkẹlẹ alawọ eeru naa lọ, o ko iwe ọkọ naa kalẹ, wọn si bẹrẹ si i dunaadura ẹ. Bi wọn ṣe n yọwo ọkọ yii niyọkuyọ, ti ọmọ naa ṣaa n ni ki wọn sanwo lo fu ẹni to fẹẹ ra mọto ọhun lara, niyẹn ba dọgbọn yi si kọrọ kan, o si tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago.
Ko pẹ rara tawọn ọlọpaa fi debẹ, wọn ba Samuel nibi to duro si, wọn beere ẹni to ni mọto to fẹẹ ta, o ni mama oun ni, ati pe mama naa mọ si boun ṣe fẹẹ ta ọkọ rẹ yii. Wọn gba nọmba mama naa lọwọ ẹ, niṣeju rẹ nibẹ ni wọn si ti pe onimọto tiyẹn fi figbe ta pẹlu iyanu.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii gẹgẹ bi Alukoro ṣe wi, lẹyin iwadii ni Owolabi yoo foju bale-ẹjọ, ibẹ ni sẹria to tọ si i yoo ti to o lọwọ.

Leave a Reply