Oyetọla, Buratai ṣedaro awọn ṣọja ilẹ wa to ku sinu ijamba ẹronpileeni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ṣapejuwe iku olori awọn ọmọ ogun ilẹ wa, Lt. Gen. Ibrahim Attahiru, to ku sinu ijamba ọkọ ofurufu lopin ọsẹ to kọja gẹgẹ bii ajalu nla ati ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Ismail Omipidan, fi sita ni Oyetọla ti ba Aarẹ Muhammadu Buhari ati gbogbo awọn mọlẹbi oloogbe kẹdun iku ọkunrin naa, to si rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati ma ṣe ṣọfọ bii awọn alaigbagbọ.

Gomina Oyetọla ṣapejuwe Attahiru gẹgẹ bii akinkanju, to ni igboya, to si ya ara rẹ sọtọ pẹlu ipinnu lati sin orileede yii pẹlu gbogbo agbara rẹ, eyi to fara han ninu aṣeyọri tileeṣẹ ologun ilẹ wa ni laarin oṣu diẹ to jẹ olori wọn.

O ṣalaye pe niwọn igba ti awọn ẹlẹsin Igbagbọ ati ti Musulumi ti gbagbọ pe ewe kan ko le ja bọ lara igi lai ṣe pe Ọlọrun to jẹ amẹda mọ si i, a ko gbọdọ ṣọfọ ọkunrin naa atawọn ti wọn jọ lugbadi iṣẹlẹ naa bii ẹni ti ko mọ Ọlọrun.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun tu gbogbo awọn mọlẹbi tiṣẹlẹ naa kan ninu, ko si duro ti aya atawọn ọmọ ti awọn oloogbe fi silẹ saye lọ.

Bakan naa ni olori awọn ọmọ ogun ilẹ wa tẹlẹ, ẹni to tun jẹ aṣoju orileede yii lorileede Republic of Benin, Tukur Buratai, ti ranṣẹ ibanikẹdun si Aarẹ Buhari atawọn abẹsinkawọ rẹ lori iku Attahiru.

O ni iku naa ba oun lojiji pupọ, o si du orileede Naijiria ni anfaani nla to wa ninu ọgbọn ti Ọlọrun fi jinki ọkunrin naa, ẹni to ni o ti ṣiṣẹ takuntakun lati gbogun ti iwa igbesunmọmi niwọnba asiko to ti lo.

Buratai fi kun ọrọ rẹ pe ẹni to ṣee mu yangan ni oloogbe naa, nitori o ti figba kan ṣiṣẹ labẹ oun, oun si mọ bo ṣe jafafa si lẹnu iṣẹ ologun to yan laayo, ati pe ti ki i ba ṣe ti iku ojiji yii, o jẹ amuyangan fun orileede Naijiria.

O ba ileeṣẹ ọmọ ogun orileede yii kẹdun iku awọn akọni naa, o tun rọ wọn lati ma ṣe jẹ ki iṣẹlẹ naa da omi tutu si wọn lọkan, ki wọn si bẹrẹ nibi ti awọn eeyan naa fi adagba rọ si.

Leave a Reply