Oyetọla ni ki wọn da awọn ileewe pada si bi wọn ṣe wa tẹlẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Atẹjade kan lati ileeṣẹ eto ẹkọ ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ni kete tawọn akẹkọọ ba ti wọle lọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ni awọn akẹkọọ yoo pada sileewe ti wọn wa tẹlẹ ki wọn too da wọn pọ mọ ileewe mi-in lasiko iṣejọba Arẹgbẹṣọla, bẹẹ lonikaluku yoo bẹrẹ si i lo aṣọ ileewe ti wọn n lo tẹlẹ, yatọ si aṣọ ẹgbẹjọda ti gbogbo akẹkọọ n lo nipinlẹ Ọṣun.

Dokita T. T. Adeagbo to fọwọ si i sọ fun gbogbo awọn ọga-agba ileewe alakọọbẹrẹ ati girama pe ni kiakia ni ki aṣẹ naa fẹsẹ mulẹ nileewe ẹnikọọkan wọn ti wọn ba ti wọle pada.

Nigba tiṣejọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla mu atunṣe ba eto-ẹkọ nipinlẹ Ọṣun lọdun 2013, ariwo gba gbogbo ilu kan, ọpọlọpọ lo ri igbesẹ naa bii inilara nla fun awọn obi ati akẹkọọ.

Ohun ti Arẹgbẹṣọla n sọ nigba naa ni pe oun fẹ ki eto-ẹkọ ipinlẹ Ọṣun da bii ti ilẹ okeere, o ni ki awọn akẹkọọ maa lo aṣọ ileewe kan naa, ki ilana si kuro ni 6-3-3-4 to wa tẹlẹ si 4-5-3-4.

O ko awọn ileewe to jẹ obinrin nikan papọ mọ awọn ileewe to ni ọkunrin, bẹẹ lo pa awọn ileewe kan rẹ, to si ko gbogbo akẹkọọ wọn lọ sawọn ileewe mi-in. O ko awọn ileewe to jẹ tawọn ileejọsin pọ mọ awọn ara wọn, bẹẹ lawọn akẹkọọ n rin bii maili mẹfa ki wọn too de ileewe tuntun tijọba ko wọn lọ.

Bi wahala naa ṣe le to, Gomina Arẹgbẹṣọla duro lori ipinnu rẹ, o de fila ma wo bẹ, ṣugbọn ko ju oṣu meji lọ ti awọn akẹkọọ bẹrẹ si i fa wahala laarin ara wọn.

Awọn to jẹ pe wọn ko lobinrin lọdọ tẹlẹ, atawọn ti ọkunrin ko si lara wọn bẹrẹ ija, wọn n lọ lati ileewe kan lati da wahala silẹ nileewe keji, nigba to si jẹ pe aṣọ-ileewe kan naa ni wọn n wọ, ko ṣee ṣe fawọn ọlọpaa lati da wọn mọ.

Arẹgbẹṣọla tun pin kọmputa alagbeeka ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọpọn-Imọ fun awọn akẹkọọ, ṣugbọn dipo kawọn ọmọ yii fi maa kọ ẹkọ to wa ninu ẹ, fiimu atawọn nnkan mi-in ni wọn n fi i ṣe.

Lẹyin ti ọdun mẹjọ iṣejọba Arẹgbẹsọla pari, ti Alhaji Isiaka Gboyega Oyetola gba ọpa-aṣẹ, o kede pe awọn araalu sọ oniruuru nnkan nipa eto-ẹkọ ipinlẹ Ọṣun lasiko toun n lọ kaakiri lati ki wọn fun bi wọn ṣe fi ibo wọn gbe oun wọle, nitori naa, o gbe igbimọ kan kalẹ, eleyii ti Ọjọgbọn Olu-Aina jẹ alaga fun lati gbe igbesẹ lori rẹ.

Lọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii, ni Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Funkẹ Ẹgbẹmọde, sọ fawọn oniroyin pe ijọba ti fọwọ si awọn aba kan to wa ninu abajade igbimọ naa.  Lara awọn aba naa ni pe kijọba da awọn ileewe pada si bi wọn ṣe wa tẹlẹ, ki wọn maa jẹ orukọ wọn, ki wọn si maa lo aṣọ-ileewe wọn.

Ni ti Ọpọn-Imọ, Ẹgbẹmọde ṣalaye pe ijọba yoo tun awọn akude to wa ninu rẹ ṣe, wọn yoo si ko o jade lọtun nitori pe o wulo pupọ ti amojuto ba wa lori ọna ti awọn akẹkọọ n gba lo o.

Awada lawọn araalu kọkọ pe ọrọ naa, wọn n beere pe ṣebi Oyetọla wa lara awọn igbimọ iṣejọba Arẹgbẹṣọla ti wọn gbe igbesẹ yẹn nigba naa, bawo ni yoo ṣe waa rọrun fun un lati yi awọn nnkan ti ọga rẹ igba yẹn ṣe pada. Ṣugbọn pẹlu ikede yii, orin ti yipada, ilu naa si ti yipada lori eto ẹkọ l’Ọṣun, inu ọpọ awọn eeyan ipinlẹ naa lo si dun si eleyii.

 

One thought on “Oyetọla ni ki wọn da awọn ileewe pada si bi wọn ṣe wa tẹlẹ l’Ọṣun

Leave a Reply