Oyetọla, Owoẹyẹ gboṣuba fun Arẹgbẹṣọla layaajọ ọjọọbi rẹ

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ki ẹni to gbaṣẹ lọwọ rẹ, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ku oriire ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelọgọta loke-eepẹ to ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Bakan naa ni abẹnugan ile-igbimọ aṣofin, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, gboṣuba fun ọmọ bibi ilu Ileṣa yii fun ipa takuntakun to ti ko ninu oṣelu, eleyii to sọ ọ di adari ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

Oyetọla, ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Ismail Omipidan, fi sita lo ti gboriyin fun iṣẹ iriju manigbagbe ti Arẹgbẹṣọla, ẹni to jẹ minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii bayii, ṣe fun ipinlẹ Ọṣun ati Naijiria lapapọ.

O darapọ mọ awọn ẹbi, ara, ọrẹ atawọn ojulumọ ninu oṣelu lati dupẹ lọwọ Allah fun anfaani to fun Arẹgbẹṣọla lati ri ọdun kẹrinlelọgọta ninu alaafia.

Oyetọla wa gbadura pe ki Ọlọrun tubọ fun olọjọọbi ni ẹmi gigun ati idunnu lati ṣe ọpọ ọdun ninu ilera pipe.

Ni ti Ọnarebu Owoẹyẹ, o ṣapejuwe Arẹgbẹṣọla gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe ti ogunlọgọ eeyan yoo maa bu mu ninu omi ọgbọn rẹ ninu oṣelu ni bayii to ti de ipo agba pẹlu iriri rẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna tẹlẹ, gomina ọdun mẹjọ ati minisita lọwọlọwọ.

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Kunle Alabi, fi sita lo ti rọ ọlọjọọbi lati ma ṣe gbagbe pe lila ipa rere ninu aye awọn eniyan ṣe pataki pẹlu akaba agba to ti gun yii.

Leave a Reply