Pasitọ Adebayọ si tan akọrin ṣọọṣi rẹ wọ yara, lo ba  fipa ba a lo pọ l’Agbado

Faith Adebóla

Egbirin ọte, ba a ṣe n pa’kan lọ’kan n ru, lọrọ ifipa ba ni lo pọ to n waye lemọlemọ laarin awọn ojiṣẹ Oluwa atawọn ọmọ ijọ wọn jẹ nipinlẹ Ogun bayii o. Ko ti i ju ọjọ meji ti ọrọ ti pasitọ to fọmọ-ijọ ẹ, ọmọọdun mẹrinla loyun, l’Owode-Ẹgba, gori afẹfẹ, ọwọ awọn agbofinro ti tun tẹ oludasilẹ ijọ ẹni ọdun mejidinlogoji mi-in, Pasitọ Isreal Adebayọ, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹgbẹ akọrin ṣọọṣi ẹ, ọmọọdun mẹrinla, loun naa ki mọlẹ, o si fipa ba a laṣepọ nigba tiyaa ọmọ naa ko si nile.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro  ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ṣọwọ si ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan-an yii, SP Abimbọla Oyeyẹmi ni iya ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa lo keboosi lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Agbado, nipinlẹ Ogun, pe ki wọn gba oun, niṣe loun lọọ tọju ara oun, tori aarẹ kan to ba oun finra eyi to mu koun rinrin-ajo, oun o si lo ju ọsẹ diẹ lọ o, ṣugbọn koun too de, Pasitọ Adebayọ to tun jẹ oludasilẹ ṣọọṣi ajihinrere “The Beloved Chapel,” toun atọmọbinrin oun n lọ ti ṣe ọmọ naa baṣubaṣu, bẹẹ ọmọ  ẹgbẹ akọrin wọn lọmọ ọhun.O ni Ojule kẹsan-an, Opopona Iyaniwura, lẹgbẹẹ Opopona Owonikoko, l’Agbado, ni ṣọọṣi naa wa.

Wọn bi ọmọbinrin naa leere bọrọ ṣe jẹ, o ni niṣe ni pasito yii tan oun wọnu yara ẹ to wa ninu ọgba ṣọọṣi ọhun, lo ba ṣe ‘kinni’ foun lọran-an-yan, ọjọ naa lo si ja ibale oun, tori ko sọkunrin to gori oun ri.

Biṣẹ o ba pẹ’ni, a ki i pẹ’ṣẹ, kia ni DPO teṣan Agbado ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe ki wọn lọọ mu afurasi ọdaran to loun ojiṣẹ Oluwa yii wa, wọn si gbe e janto de teṣan.

Nigba ti wọn beere ọrọ lọwọ ẹ, o ni gẹgẹ bii ojiṣẹ Oluwa, oun ko gbọdọ purọ, ootọ loun huwa ainitiju naa, o loun fipa ba ọmọ naa laṣepọ ni tododo.

O ṣalaye p’oun o tiẹ m’ohun to ba oun dedii iru iwa bẹẹ o, tori oun o ro o tẹlẹ, bi gbogbo ẹ ṣe ṣẹlẹ gan-an ṣi n jọ oun loju ni, amọ ki wọn ṣaa ba oun bẹ ọmọbinrin naa atawọn mọlẹbi ẹ ni, tori ọbẹ ti ge ọmọ lọwọ, ọmọ ibaa si sọ’bẹ nu, ọbẹ kuku ti pari ohun to fẹẹ ṣe.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni  ṣaaju akoko yii lawọn ọlọpaa iba ti lọọ mu ọdaran yii, tori latinu oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, niṣẹlẹ ọhun ti waye, bi wọn ṣe wi, ṣugbọn mama ọmọbinrin naa ko kọkọ fẹ kọrọ naa di tọlọpaa, ko si fẹ ki wọn mu afurasi naa, o ni ẹni ọwọ lawọn ojiṣẹ Oluwa.

Amọ nigba ti ẹjẹ bẹrẹ si i jade loju ara ọmọ ẹ, tẹjẹ naa si kọ ti ko duro, eyi lo mu kiyaa yii kegbajare sawọn agbofinro. Wọn lọsibitu tọmọbinrin naa ti n gba itọju lo ṣi wa di ba a ṣe n sọ yii.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ ki wọn fi Pasitọ Isreal Adebayọ ṣọwọ sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n wa fin-in idi koko iwa ifipa ba ni lo pọ ati iwa ọdaran abẹle lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweeran, Abẹokuta. Latibẹ ni wọn ti maa taari oludasilẹ ijọ yii siwaju adajọ lọgan tiwadii ba ti pari

Leave a Reply