Pasitọ Anifowoṣe ti wọn ba awọn ọmọde ni ajaalẹ ṣọọṣi rẹ ti foju bale-ẹjọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Olusoaguntan ijọ The Whole Bible Believer, to wa lagbegbe Valentino, niluu Ondo, David Anifowoṣe, atawọn amugbalẹgbẹẹ rẹ mẹrin ni wọn ti n kawọ pọnyin rojọ lọwọ nile-ẹjọ Majisireeti tuntun to wa lagbegbe Oke-Ẹda, l’Akurẹ.

Awọn yooku ti wọn n jẹjọ lọwọ pẹlu baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọta naa ni Pasitọ Josiah Peter, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta, Stephen Ọlawọle, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta, Blessing John, ẹni ọgọta ọdun ati Ayembọ Gbenga to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta.

Awọn olujẹjọ ọhun ni Agbefọba, Augustine Omhenimhen, fẹsun kan pe wọn gbimọ-pọ lati huwa ijinigbe, eyi to lodi labẹ ofin ipinlẹ Ondo.

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si awọn afurasi naa lẹsẹ lasiko igbẹjọ to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ati Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni titi awọn ọmọbinrin kan to n jẹ Elizabeth Reuben mọle lọna aitọ, ti wọn si tun kọ lati gba obi awọn ọmọ naa laaye ki wọn maa ri wọn.

Ẹsun mi-in ti wọn tun fi kan wọn ni gbigba iyawo atawọn ọmọ Patrick Ọlaniyan, eyi ti wọn lo lodi si ifẹ inu ọkọ rẹ, bẹẹ ni wọn tun kuna lati gba ọkunrin naa laaye lati maa yọju sawọn ẹbi rẹ.

Wọn ni awọn olujẹjọ ọhun  fi ọgbọn ẹwẹ mu ọmọbinrin kan, Priscilla Ọlọrunyọmi, tira eyi to ṣe idena fun un lati tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ.

 

Ẹsun mi-in ti wọn tun n jẹjọ rẹ lọwọ ni pe wọn ti awọn ọmọ ijọ wọn mọle lọna aitọ si agbegbe ti ko fararọ fun wọn, nibi ti wọn ti le ko aisan, ti wọn si tun di wọn lọwọ lati lo ominira wọn gẹgẹ bo ṣe tọ labẹ ofin.

Paripari awọn ẹsun bii mẹwaa ti wọn fi kan Pasitọ Anifowoṣe atawọn ọmọlẹyin rẹ ni kiko awọn ọmọbinrin keekeekee tira lai gba aṣẹ lati ọdọ obi awọn ọmọ naa, ati ṣiṣe ọlọpaa kan, Ripẹtọ Rotimi Ogunji, baṣubaṣu lasiko to wa lẹnu iṣẹ rẹ.

Gbogbo awọn ẹsun ọhun ni wọn lo lodi, to si tun ni ijiya labẹ abala ofin okoolelugba le marun-un (225), ọtalelọọọdunrun le ẹyọ kan (361), ọtalelọọọdunrun le mẹrin (364), ọtalelọọọdunrun ati marun-un (365) ati okoolelẹẹdẹgbẹta din mẹrin (516).

Agbẹjọro awọn olujẹjọ, Ọladele Ayọọla, ninu ẹbẹ rẹ rọ ile-ẹjọ lati ma ṣe ti awọn eeyan ọhun mọle titi ti oun yoo fi lanfaani ati ṣe ohun to yẹ lori ọrọ gbigba beeli wọn.

 

Idi ree ti Onidaajọ O. R. Yakubu fi paṣẹ pe kawọn olujẹjọ ọhun si maa ṣere wọn ni atimọle awọn ọlọpaa titi ti igbẹjọ mi-in yoo tun fi waye.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja lọhun-un, lawọn ọlọpaa fi pampẹ ofin gbe Pasitọ Anifowoṣe atawọn ọmọlẹyin rẹ lori ẹsun kiko awọn eeyan bii mẹtadinlọgọrin tira lọna aitọ ninu sọọsi kan ti wọn n pe ni The Whole Bible Believer, eyi to wa lagbegbe Valentino, niluu Ondo.

Leave a Reply