Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kejila yii, lọwọ tẹ Pasitọ Peter Taiwo, ti ijọ Christ Apostolic Bible Church, Alaja Oke, Ṣajẹ, niluu Abẹokuta, pẹlu obinrin to wa lẹgbẹẹ rẹ, Elizabeth Taiwo ti i ṣe iyawo rẹ ti wa lahaamọ ijọba bayii. Eyi ko sẹyin ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) ti pasitọ yii fipa ba lo pọ, to si jẹ iyawo rẹ yii lo ṣatọna bi ibalopọ ipa naa ṣe waye.
Wọn mu awọn mejeeji lẹyin ti ọmọ ti pasitọ fipa ba sun lọọ sọrọ naa fun wọn ni teṣan ọlọpaa Adatan, l’Abẹokuta.
Ọmọbinrin naa ṣalaye pe akọrin loun ni ṣọọṣi ọhun, oun si lọ sibẹ nirọlẹ ọjọ naa fun igbaradi tawọn akọrin maa n ṣe ni.
O ni boun ṣe de ṣọọṣi loun ri iyawo pasitọ, obinrin naa si ni koun lọọ ba pasitọ ninu ile, nitori wọn fẹẹ ran oun niṣẹ kan.
Ọmọdebinrin naa ni eyi loun gbọ toun fi wọle lọọ ba Pasitọ Taiwo, ṣugbọn boun ṣe wọle ni iyawo rẹ tilẹkun lati ita, o ti oun ati ọkọ rẹ mọnu yara. O ni lẹsẹkẹsẹ ni Pasitọ Taiwo ti ki oun mọlẹ, to fi gbogbo agbara rẹ mu oun, to si fipa ba oun sun, to gba ibale oun.
O ni nibi toun ti n sunkun lẹyin ti pasitọ ṣetan ni iyawo rẹ ti wọle wa, niṣe lo si ni koun ma sunkun mọ, koun ka a sara bẹẹ, oun naa ti di obinrin niyẹn, ko ju bẹẹ lọ.
Ọmọge naa fi kun un pe iyawo pasitọ kilọ foun pe oun ko gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ naa fun ẹnikẹni o, nitori boun ba fi le sọ pẹnrẹn, iku ni.
Ṣugbọn ọmọ yii ko fi ti ihalẹ iyawo pasitọ ṣe, o mẹjọ lọ si teṣan Adatan, awọn ọlọpaa si ba a debẹ, ni wọn ba fọwọ ofin mu pasitọ atiyawo ẹ, o di agọ wọn.
Nigba ti wọn n jẹwọ ẹṣẹ fọlọpaa, Pasitọ Taiwo atiyawo ẹ sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, iyawo jẹwọ ipa to ko, ọkọ naa si sọ bo ṣe sọ ọmọ ọlọmọ di alaini ibale mọ. Ṣugbọn wọn ni ki i ṣe ẹjọ awọn naa, wọn ni iṣẹ Eṣu ni.
CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn gbe wọn lọ si ẹka to n ri si ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe, awọn tọkọ-taya yii si ti wa lahaamọ ẹka naa. Awọn ọlọpaa si ti gbe ọmọ ti wọn tẹtọ ẹ mọlẹ lọ si ọsibitu fun itọju.