Pasitọ to fipa bọmọ ọdun mẹrinla sun l’Ekoo ta ṣọọṣi ẹ, lo ba salọ

Faith Adebọla, Eko

Oriṣiiriṣii ẹsun ati ẹri ni wọn ko kalẹ nile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, latari ẹsun ti wọn fi kan Pasitọ Chris McDouglas Omosokpea, wọn lọkunrin to pera ẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun naa fipa ba ọmọ ijọ ẹ kan, ọmọ ọdun mẹrinla, laṣepọ, lo ba tori ẹ fa ṣọọṣi ẹ ta, o sa lọ.

Ile-ẹjọ Majisreeti to wa lagbegbe Ọgba, nipinlẹ Eko, ni igbẹjọ naa ti waye, awọn ọmọ ijo tọkunrin naa da silẹ to pe ni Peculiar Generation Assembly Church, to wa l’Oṣodi, ni wọn waa jẹrii ta ko o.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Chris ti n jẹjọ fun ẹsun ifipabanilopọ tẹlẹ  nile-ẹjọ naa, ọmọ ọdun mẹrinla kan ni wọn lo ba ṣeṣekuṣe, wọn lọdun mẹrin lo ti n ṣe kinni fọmọ ọlọmọ ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun, igba ti aṣiri tu lawọn obi ọmọ naa lọọ fẹjọ sun awọn agbofinro teṣan ọlọpaa Makinde, l’Oṣodi, ti wọn si mu un ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020, ti wọn wọ ọ lọ sile-ẹjọ.

Ile-ẹjọ gba beeli ẹ nigba to ṣaroye pe ara oun ko ya, oun fẹẹ lọọ gba itọju, lai mọ pe ki i ṣe ọrọ ailera lo n ṣe e, o n wa ọna ati sa lọ ni.

 

Ninu alaye tawọn ọmọ Ìjọ rẹ ṣe  niwaju adajọ, wọn ni bi ọkunrin naa ṣe dele, ko sọ fẹnikan to fi ṣeto tita ṣọọṣi naa mọ awọn lori, bo si ṣe ta a tan lo dawati.

Wọn ni iyalẹnu lo jẹ fawọn ọmọ ijọ naa nigba ti wọn de ṣọọṣi ọhun lọjọ kan, ti wọn ni kawọn lọọ jọsin, ṣugbọn katakata ni wọn ba to n ṣiṣẹ nibẹ, wọn ti wo ṣọọṣi palẹ, ẹni to ṣẹṣẹ ra a lo bẹrẹ iṣẹ nibẹ.

Ọkan lara awọn ẹlẹrii naa, Abilekọ Elizabeth sọ pe ohun tawọn n gbọ nipa afurasi ọdaran ọhun ni pe o ti lọọ da ṣọọṣi silẹ nibi kan to jinna, o lawọn ko ti i mọ pato ibi to sa lọ, ṣugbọn agbegbe Lẹkki, nitosi Ajah, lawọn gburoo ẹ si.

Adajọ-binrin Ejiro Kubeinje to jẹ Aarẹ ile-ẹjọ naa ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa wa olujẹjọ naa ri, nibikibi to ba fara pamọ si, ki wọn si wọ ọ dele-ẹjọ.sun igbẹjọ to kan si ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin, to n bọ.

Leave a Reply