Faith Adebọla, Eko
Bii ere ori itage ni iran ọhun jọ, ṣugbọn ki i ṣe fiimu rara, ohun to ṣẹlẹ gidi ni, ojiṣẹ Ọlọrun kan, Biṣọọbu Samson Bẹnjamin, lo ṣadeede gbe posi ru lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, o si n fi ẹrọ abugbẹmu kede pe Ọlọrun ni koun jẹ kawọn eeyan mọ pe ibinu oun ti wa lori ijọba to wa lode yii.
Kaakiri agbegbe Festac, nipinlẹ Eko, ni alaboojuto agba (General Overseer) ijọ Resurrection Praise Ministry ti kede iṣẹ to ni Ọlọrun ni koun jẹ fawọn to n ṣejọba orileede yii lọwọ lasiko yii, paapaa olori ijọba apapọ, Aarẹ Muhammadu Buhari.
Ọkunrin naa ni laye atijọ, laye igba ti wọn n kọ Bibeli, ami ati apẹẹrẹ ni Ọlọrun fi maa n ran awọn ojiṣẹ rẹ to ba fẹẹ ranṣẹ pataki si awọn onṣejọba.
“Ohun ti mo n ṣe yii lawọn ojiṣẹ Ọlọrun laye ọjọun ṣe. Ọlọrun sọ fun mi pe: ‘Lọọ gbe posi kan si ori rẹ, ki i ṣe posi olowo nla o, ami pe nnkan kan o wulo mọ, nnkan ti wọn gbọdọ sọnu ni.
“Ọlọrun ni inu oun o dun si awọn to n ṣejọba yii, ki i ṣe awọn to n ṣejọba nikan o, atawọn to aṣaaju ẹsin, atawọn lọba lọba alaṣẹ ilu pẹlu.”
Benjamin ni igbe tawọn eeyan n ke lasiko yii yẹ ko mu ijọba ronu, ki wọn si jokoo lati yẹ ẹ wo boya awọn nnkan tawọn to so wa po gẹgẹ bii orileede kan ṣi wa nibẹ tabi o ti sọnu. O ni to ba ti sọnu, wiwa papọ bii orileede kan yoo ṣoro gan-an.
Bayii lawọn eeyan sọ ọkunrin naa di iran apewo bo ṣe n ru posi kaakiri. Ojiṣẹ Ọlọrun naa ni oun maa lọọ jiṣẹ ọhun lawọn ile ijọba bi ẹmi Ọlọrun ba ṣe dari oun.