Patako ipolongo Ọṣinbajo fun ipo aarẹ lu ipinlẹ Kwara pa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i jade lati fi erongba rẹ lati dupo aarẹ ilẹ Naijiria han, ṣugbọn o fẹrẹ jẹ tibu tooro ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni patako ipolongo Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti wa bayii.

Lara awọn agbegbe ti ALAROYE de, ti wọn ri awọn patako ipolongo ati posita Yẹmi Ọṣinbajo mọ ni Opopona Fate, Airport, Geri Alimi, ikorita Unity si Post Office, ati agbegbe Taiwo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ‘Kwara Alliance for Yemi Ọṣinbajo 2923’ ni wọn kora jọ si papa-iṣere ipinlẹ naa to wa niluu Ilọrin, ti wọn n lulu, ti wọn si n jo. Bakan naa ni wọn n kọrin, ‘Ọṣinbajo fun Aarẹ lọdun 2023’, wọn ni oun nikan lo le mu ayipada rere ba orilẹ-ede Naijiria.

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii ni wọn ṣi wa nibẹ.

 

Leave a Reply