Pelu bi eto ọrọ-aje ṣe denukọlẹ, ijọba mi ko ni i gbaṣẹ lọwọ oṣiṣẹ kankan- Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lasiko to n sinu aawẹ pẹlu awọn Musulumi lalẹ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ni gbọngan asa igbalode Doomu, to wa loju ọna Igbatoro, niluu Akurẹ, ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti sọ pe oun ko ṣetan lati gba iṣẹ lọwọ eyikeyii ninu awọn oṣiṣẹ ijọba latari eto ọrọ aje orilẹ-ede to n saisan lọwọ.

Arakunrin ni loootọ la ti ri awọn ipinlẹ bii Kaduna to gba iṣẹ lọwọ ọgọọrọ awọn oṣiṣẹ, nigba tawọn mi-in kọ jalẹ lati maa san ẹgbẹrun mejidinlogun to jẹ owo awọn oṣiṣẹ to kere ju lọ, ṣugbọn ti oun ko ṣetan ati ṣe bẹẹ ni toun.

O ni ẹbẹ loun n bẹ awọn oṣiṣẹ ki wọn tubọ mu suuru fun ijọba laarin asiko yii ti nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ feto ọrọ aje ipinlẹ Ondo nitori pe gbogbo ẹtọ wọn ko ni i sai tẹ wọn lọwọ nigbakuugba ti nnkan ba ti n ṣenuure.

Lati bii oṣu mẹfa sẹyin lọkan-o-jọkan ede aiyede ti n suyọ laarin ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ naa latari bi wọn ko ṣe rowo osu wọn san deedee mọ bii ti atẹyinwa.

Ẹkọọkan tijọba ba si tun fẹẹ sanwo, aabọ owo-osu ni wọn n ri san, eyi lo si ṣokunfa bawọn oṣiṣẹ eto ilera, awọn dokita atawọn nọọsi ṣe bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ loṣu bii meji sẹyin.

Ko ti i ju bii ọsẹ meji lọ sasiko yii nigba ti wọn ṣẹṣẹ pada ṣẹnu iṣẹ wọn.

Wahala mi-in tun fẹẹ su yọ laarin ijọba atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lọsẹ to kọja yii pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ san ida ọgọta fawọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii owo-oṣu keji, eyi ti ẹgbẹ awọn nọọsi yari kanlẹ pe awọn ko ni i gba lọwọ ijọba.

 

Leave a Reply