Peter fun ọmọ to bi ninu ara rẹ lo loyun l’Ondo, lo ba lo ṣeeṣi ni

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, ti ni ki wọn i lọọ fi ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan, Peter Moses, pamọ sọgba ẹwọn na, lori ẹsun pe o fun ọmọ bibi inu ara rẹ, Peter Patience, loyun.

 

Iṣẹlẹ yii waye niluu Asẹwele-Korede, nijọba ibilẹ Odigbo, nibi ti olujẹjọ naa ti fipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun ọhun lo pọ titi to fi doyun laarin osu kọkanla, ọdun to kọjasi osu kin-in-ni, ọdun tuntun ta a wa yii.

 

Agbefọba, Ripẹtọ Jimoh Amuda, ni afurasi ọhun ti ṣẹ si abala kejilelọgbọn ninu iwe ofin orilẹ-ede yii ti ọdun 2003, eyi to lodi si lilo ọmọde nilokulo.

 

Agbefọba ọhun rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju diẹ kawọn ọlọpaa fi pari iwadii ti wọn n ṣe lọwọ.

 

Ni kete ti wọn ti ka ẹsun kan soso ti wọn fi kan olujẹjọ naa tan lo ti gba pe oun jẹbi, to si n bẹbẹ pe ki adajọ siju aanu wo oun nitori pe aiṣe ko kan ọgbọn.

 

Onidaajọ F. O. Ọmọfọlarin ni ki wọn i lọọ fi ọkunrin naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Leave a Reply