Saheed to fipa ba ọmọọdun mẹrinla laṣepọ foju bale-ẹjọ

Faith Adebọla, Eko

Ahamọ ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo, nile-ẹjọ Majisreeti to wa n’Ikẹja paṣẹ pe ki wọn fi baale ile ẹni ọgbọn ọdun, Saheed Safuraini, si. Ọmọ ọdun mẹrin ni wọn lo fipa ba laṣepọ.

Ijọba lo wọ afurasi ọdaran naa re’le-ẹjọ latari bawọn obi ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri kan ṣe waa fẹjọ ẹ sun pe o ṣakọlu sọmọ awọn lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, to si fipa ṣe kinni fọmọbinrin naa.

Gẹgẹ bi alaye ti Agbefọba Kẹhinde Ajayi ṣe ni kootu ṣe lọ, o ni iwadii tawọn agbofinro ṣe fihan pe loootọ ni afurasi ọdaran yii ṣe ọmọ ọlọmọ baṣubaṣu, ayẹwo tawọn dokita si ṣe lẹyin naa fihan pe ẹnikan ti huwa aidaa sabẹ ọmọbinrin ọhun.

O ni lasiko tọmọbinrin ọhun n lọọ jiṣẹ tawọn obi rẹ ran an lọjọ naa lafurasi ọdaran yii fọgbọn tan an wọle rẹ to wa ni Opopona Ida-Aba, lagbegbe Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, o niwa ọdaran naa ta ko ofin iwa ipinlẹ Eko, o si tun da omi alaafia adugbo naa ru.

Afurasi ọdaran loun ko jẹbi, o si rawọ ẹbẹ si adajọ kootu naa, Abilekọ A. O. Ajibade, pe ko yọnda foun lati maa tile waa jẹjọ.

Ṣugbọn Adajọ Ajibade ni ki wọn da a pada sẹwọn titi di ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹwaa, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju. O ni ki wọn ko faili ẹjọ naa lọ si ẹka to n fawọn adajọ nimọran.

Leave a Reply