Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọmọde ati obinrin nipinlẹ Ọṣun ti fa ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Sanjọ le awọn ọlọpaa lọwọ lori ẹsun pe o lu ọmọ rẹ pa.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin ileeṣẹ naa, Bọlarinwa Adereti, fi sọwọ si ALAROYE lo ti ṣalaye pe nigba ti Kọmiṣanna awọn, Olubukọla Ọlabọọpo, gbọ si iṣẹlẹ naa lo fa ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji naa le ọlọpaa lọwọ.
Gẹgẹ bi Ọlabọọpo ṣe sọ, agbegbe Alekuwodo, niluu Oṣogbo, ni ọkunrin naa n gbe pẹlu iyawo rẹ, awọn eeyan agbegbe naa ni wọn si fi iṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ awọn leti.
Ninu akọsilẹ Sanjọ lo ti ṣalaye pe ọdun 2008 loun atiyawo oun fẹra awọn, ọmọ marun-un ni wọn si bi. O ni ipo kẹta lọmọ ti oun ṣeesi lu pa yii wa.
O sọ siwaju pe “Iyawo mi fi ọmọ yẹn ti mi lọjọ yẹn, bo ṣe bẹrẹ si i sunkun niyẹn, mo rẹ ẹ titi, ṣugbọn ko gbọ, bi ẹmi kan ṣe wọnu mi niyẹn pe ki n lu u pa a.
“Ko ti i ju ọmọ oṣu meji lọ nigba naa, bi mo ṣe ṣeesi lu u pa niyẹn. Inu oko ni emi atiyawo mi lọọ sin in si lọjọ naa.”
Ṣugbọn ninu ọrọ iyawo Sanjọ, o ni ọmọ marun-un lawọn bi loootọ, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo ti oun n gbe dani lo ṣẹku nitori awọn mẹrin ti ku.
Lori ọna ti wọn gba ku, iyawo Sanjọ ṣalaye pe oun ati ọkọ oun gbimọ-pọ lati pa awọn ọmọ meji latari wahala aini ati oṣi to n ba awọn finra, bẹẹ ni awọn gbe ikẹta sọnu si agbegbe Technical School, niluu Oṣogbo, ẹkẹrin si ni ọkọ oun lu pa yẹn.
Lẹyin akọsilẹ ọkunrin yii ni wọn fa a le awọn agbofinro lọwọ fun iwadii to jinlẹ lori ọrọ rẹ. Ọlabọọpo waa kilọ pe ijọba ipinle Ọṣun ko ni i faaye gba ki ẹnikẹni huwa aitọ si awọn ọmọde ati pe ijiya n duro de ẹnikẹni to ba ṣan aṣọ iru ẹ ṣoro.