Sanwo-Olu ṣebura fun igbimọ oluwadii ẹsun SARS, o fi nọmba tawọn eeyan le maa pe sita

Faith Adebọla, Eko

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde yii, ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ṣebura fun igbimọ ẹlẹni mẹfa kan ti yoo gbọ ẹsun tawọn araalu ba mu wa lodi si iwakiwa ikọ SARS. Lọfiisi gomina to wa ni Alausa, Ikẹja ni ibura ọhun ti waye.

Bakan naa ni gomina tun kede adirẹsi ifiweranṣẹ atawọn nọmba tẹlifoonu tawọn araalu to fẹẹ mu ẹsun wa maa fi kan si igbimọ oluwadii ọhun.

Adirẹsi ifiweranṣẹ naa ni: judicialpanelonsars@lagosstate.gov.ng; nigba ti nọmba tẹlifoonu wọn jẹ 09010513203, 09010513204 ati 09010513205.

Gomina gba awọn ọmọ igbimọ naa niyanju pe ki wọn fọwọ pataki mu iṣẹ yii, ki wọn ma si fi igba kan bọ ọkan ninu, nitori niṣe ni ijọba fẹẹ fidi idajọ ododo mulẹ, wọn fẹẹ bu ororo itura sọkan awọn eeyan ti ikọ SARS ti pọn loju sẹyin.

Sanwo-Olu ni gbogbo ẹsun yoowu ti wọn ba mu wa siwaju wọn ni ki wọn fara balẹ ṣayẹwo rẹ, ki wọn si pese imọran to yẹ ki ijọba gbe lori ọrọ naa.

Adajọ-fẹyinti Doris Okuwobi ni wọn bura fun gẹgẹ bii alaga igbimọ tuntun ọhun.

Awọn ọmọ igbimọ marun-un to ku ni: Amofin agba Ẹbun Adegboruwa, Ọlọpaa-feyinti DIG Taiwo Lakanu, Abilekọ Patience Udoh, Ọgbẹni Ṣẹgun Awosanya to jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, ati Abilekọ Olutoyin Odusanya. Oṣu mẹfa ni wọn yoo fi ṣiṣẹ wọn.

Gomina ni oun dabaa pe ki awọn ọdọ fi eeyan meji ranṣẹ lati ṣoju fun wọn, ki wọn si le maa wo bi nnkan ba ṣe n lọ si, nigba ti igbimọ naa ba bẹrẹ si i jokoo.

O tun fi anfaani naa parọwa sawọn ẹlẹyinju aanu lati da si eto ikowojọ igba miliọnu naira (N200 million) lati fi ran awọn ti wọn ba fẹri ẹ mulẹ pe loootọ ni SARS ti fiya jẹ wọn lọna aitọ kan, lọwọ. O ni ijọba oun gba lati gbọ ohunkohun tawọn araalu ba lawọn n fẹ, tori araalu gan-an lo ni agbara.

Leave a Reply