SARS: Ileeṣẹ ọlọpaa ko san aadọta miliọnu tile-ejọ ni ki wọn san fun mi latọdun 2016 – Bankọle

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọkan lara awọn to fiwe ẹsun ranṣẹ si igbimọ to n gbọ awuyewuye ta ko SARS, Diakoni Samuel Bankọle, ti ni ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati san aadọta miliọnu naira tile-ẹjọ paṣẹ fun wọn lati san foun lati ọdun 2016 nitori bi wọn ṣe tẹ ẹtọ oun loju.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i ṣalaye lẹkun-unrẹrẹ bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa tipinlẹ Kwara ati Edo lo pe lẹjọ nigba naa, titi di asikọ yii, wọn kọ lati mu aṣẹ ile-ẹjọ ṣẹ.

Iwe ẹsun mejidinlogun ọtọọtọ nigbimọ to n gbọ awuyewuye ta ko ọlọpaa SARS, ti ri gba nipinlẹ Kwara. Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nijokoo wọn bẹrẹ.

Alaga igbimọ naa, Adajọ-fẹyinti  Babatunde Garba, ṣalaye lọjọ Aje, Mọnde, pe awọn ti fi iwe-ẹsun tawọn araalu kọ naa ranṣẹ sileeṣẹ ọlọpaa lati fesi si i. O ni mẹrin pere ni wọn ṣi fesi si.

Garba ni igbimọ naa ti kọwe ranṣẹ sawọn akọṣẹmọṣẹ atawọn ajọ ti ki i ṣe tijọba, to fi mọ ajọ ẹlẹsin mejeeji (Kristẹni ati Musulumi) lati gba imọran wọn fun aṣeyọri iṣẹ tijọba gbe le wọn lọwọ naa.

O ni oun nigbagbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo fesi si awọn ẹsun yooku tawọn ti fi ranṣẹ si wọn bi ijokoo naa ba ṣe n lọ.

Ni tiẹ, Alaga ẹgbẹ awọn amofin, Nigerian Bar Association (NBA) ẹka tilu Ilọrin, Abdulganiy Bello, fi da igbimọ naa loju pe awọn yoo gbẹjọ ro lọfẹẹ fun gbogbo awọn to ba fiwe ẹsun nipa SARS ranṣẹ.

Igbimọ ọhun ti sun ẹjọ wọn si ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Leave a Reply