Serikin Fulani lo wa nidii bawọn Fulani ṣe waa paayan rẹpẹtẹ n’Igangan – Aṣigangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Aṣigangan tilu Igangan, Ọba Azeez Ọlawuyi, ti sọ pe Sariki Fulani, iyẹn ọba awọn Fulani ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Saliu Abdulkabir, to sa kuro niluu Igangan laipẹ yii lo wa nidii ikọlu ti awọn Fulani ṣe sinu ilu naa.

O ni ọga awọn Fúlàní naa ti sọ asọtẹlẹ nipa ikọlu naa, ṣugbọn ko sẹni to mọ pe ọna to lagbara to bẹẹ lọkunrin naa yoo gba mu ileri ẹ ṣẹ.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejilelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, lolori awọn Fulani naa sa kuro niluu Igangan latari bi ajafẹtọọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho), ṣe kilọ fawọn to n huwa ọdaran laarin awọn Fulani agbegbe Oke-Ogun lati fi agbegbe naa silẹ bi wọn ko ba fẹ ki oun kogun ja wọn.

Awọn ara Igangan ati agbègbè Ibarapa lapapọ ti wọn ba ALAROYE sọrọ gba pe awọn Fulani ni wọn huwa ọdaran naa nitori ti wọn gba pe awọn Yorùbá, paapaa, Sunday Igboho, lo le ọga awọn kuro niluu Igangan.

Gẹgẹ bi Aṣigangan ṣe fidi ẹ mulẹ ninu ifọrọwọrọ pẹlu akọroyin wa, “Eeyan ti wọn pa to mẹẹẹdogun, bẹẹ ni wọn dana sun ile rẹpẹtẹ kaakiri.

“Awọn Fulani ni wọn ṣiṣẹ yẹn. Seriki Fulani ti sọ pe oun n bọ waa gbẹsan lile ti wọn le oun kuro niluu. Bẹẹ si ree, funra Seriki lo lọ, ki i ṣe pe ẹnikan lo le e. Ko pẹ sigba to lọ tan naa lo ranṣẹ pada lati ibi to wa lọhun-un pe oun n pada bọ waa gbẹsan.

“Ni nnkan bíi aago mejila oru mọ́jú Satide to kọja ni wọn ṣigun dé. Bẹẹ ni won n pa awọn èèyàn, tí wọn sì n dana sunle kaakiri.

“Eeyan bii mẹẹẹdogun ni wọn pa. Ile ti wọn dana sun naa to mẹẹẹdogun. Aafin mi paapaa wa lara ibi ti wọn dana sun, wọn jo o ku eeru gburugburu. Ọlọrun lo yọ awọn mọlẹbi mi to wa ninu ile, diẹ lo ku ki won ri wọn jo mọle. Emi ko sí sí laafin lasiko yẹn ni temi.

“Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti wa, wọn sì ti ṣeleri lati gbe igbesẹ to ba yẹ lori iṣẹlẹ yii. Ẹbẹ la bẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ atijọba apapọ lati gba wa lọwọ awọn to n pa wa lojojumọ wọnyi”

 

 

 

Leave a Reply