Suleman lu wolewole to fẹẹ yẹ ileegbọnsẹ rẹ wo, ladajọ ba sọ ọ sẹwọn oṣu mẹta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin ni Alagba Ọganla Suleman, ṣugbọn kootu  Majisreeti ilu Abẹokuta ti ran an lẹwọn oṣu mẹta bayii, oun ati ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan torukọ tiẹ n jẹ Kẹhinde Afuapẹ, ni ile-ejọ ju sẹwọn, nitori wọn ba wolewole ja lasiko tiyẹn n ṣiṣẹ tijọba gbe fun un.

Aṣoju ijọba ni kootu, Inspẹkitọ Lawrence Olu- Balogun, ṣalaye pe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja, awọn olujẹjọ mejeeji yii lu obinrin kan to jẹ wolewole torukọ ẹ n jẹ Ọnalabi Funkẹ, l’Ojule kẹrindinlaaadọta, agbegbe Ikereku Idan, l’Abẹokuta.

Ki i ṣe pe wọn lu u nikan kọ, agbefọba sọ pe wọn tun fa aṣọ ẹ ya. O ni ẹka ilera to wa ni Ariwa Abẹokuta ni Funkẹ n ba ṣiṣẹ, ibẹ ni wọn ti ran an lọ si Ikereku Idan lati wo awọn ohun to yẹ ni wiwo gẹgẹ bii wolewole.

Ounjẹ ni Kẹhinde Afuapẹ n ta, wolewole si beere iwe to fi lẹtọọ lati maa ta ounjẹ, bẹẹ lo ni ki Alagba Suleman jẹ koun wo ile igbọnsẹ to n lo ninu ile naa, ohun to fa wahala ree gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi, to di pe awọn mejeeji yii lu wolewole obinrin naa ti wọn tun fa aṣọ rẹ ya.

Iwa ti wọn hu yii lodi sofin, abala okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (516, ati abala karundinlogoji,35) iwe ofin ti wọn ṣe lọdun 2006 nipinlẹ Ogun lo lodi si i gẹgẹ bo ṣe sọ.

Adajọ Dẹhinde Dipẹolu sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe awọn mejeeji yii jẹbi ifiyajẹ ẹni to n ṣiṣẹ rẹ bijọba ṣe ran an. O ni ki wọn lọọ ṣẹwọn oṣu mẹta fun ẹṣẹ naa, ko si faaye owo itanran silẹ fun wọn rara.

 

Leave a Reply