Dada Ajikanje
Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, ti sọ pe bii ẹni da awọn iran ẹ ni iwa ti Ọọni Ile-
Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunusi, hu lasiko to lọọ ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari.
O ni bi Ọba Adeyẹye ko ṣe ṣalaye ohun ti awọn Fulani darandaran n foju awọn ọmọ Yoruba ri, bii ẹni ṣojo ni niwaju Buhari, ati pe iwa ọdalẹ ni paapaa latọwọ ọba alaye si awọn eeyan ẹ.
Lọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lọkunrin ajijagbara fun iran Yoruba yii sọrọ naa lasiko to ba awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa loke okun ṣepade lori ẹrọ alatagba.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe o ṣe ni laaanu pe ọba yii kọ lati sọ idaamu ati adanu nla ti awọn Yoruba ti ko lọwọ awọn Fulani darandaran ti wọn gba lalejo lagbegbe wọn, ṣugbọn ti wọn pada di ọran si wọn lọrun.
Igboho sọ pe ohun to ba eeyan lọkan jẹ ni bi Ọọni ko ṣe fẹhonu awọn eeyan ẹ han si Aarẹ nipa ohun ti awọn Fulani n ṣe nigba to dewaju Muhammadu Buhari.
Bakan naa lo sọ pe pupọ ninu awọn ọba alaye ni wọn n bẹru lati sọ ootọ bayii lori ọrọ to wa nilẹ naa, bẹẹ lo tun fi kun un pe pupọ ninu wọn gan-an ni wọn ko fẹẹ faaye gba awọn mọ laafin nitori ẹru to n ba wọn.
Igboho sọ pe, ko yẹ ki atimọle tabi idunkooko-mọ-ni lati ọwọ ijọba maa jẹ ohun ijaya fun awọn ọba alaye yii bi ko ṣe pe ẹyin awọn eeyan ilu wọn lo yẹ ki wọn wa.
O ni, “Nigba ti Ọọni Ile-Ifẹ dewaju Buhari, ọba yii kọ lati sọ ootọ to wa nidii ọrọ yii, nigba to si pada de, emi lo doju kọ,to ni ki n fi ija silẹ fun ijọba lati ja, iru ọrọ wo niyẹn. Alaafin ti pe mi, ohun to dun mi ju ni pe Alaafin gan-an lo yẹ ki Buhari pe, ki i ṣe Ọọni Ile-Ifẹ to ri ootọ ọrọ ti ko sọ.
“Ọọni ja awa ọmọ Yoruba kulẹ lori ohun to ṣe niwaju Buhari, bẹẹ ni inu mi ko dun rara, nitori ẹ gan-an ni mi o ṣe dahun nigba ti Ọba Ogunwusi pe mi. Gbogbo ọba alaye ti ko ba ti ṣe tiwa lori ohun ti a dawọ le yii, tiru wọn ba pe mi, emi o ni i lọ, o to gẹẹ, ohun ti awọn Fulani ṣe fun wa nilẹ Yoruba to gẹẹ”