Lẹẹkan si i, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ọkunrin ajafẹtọọ iran Yoruba nni ti ṣapejuwe Aṣiwaju Bọla Tinubu, Gomina Ṣeyi Makinde atawọn eeyan kan ti awọn Yoruba n pe ni aṣaaju wọn gẹgẹ bii ẹru Fulani ti wọn ti kuna lati duro ti awọn eeyan wọn ninu wahala ti wọn n la kọja.
Eyi wa lara awọn koko ọrọ pataki to sọ lasiko ipade ti akikanju ọmọ Yoruba yii ṣe pẹlu awọn ọmọ Yoruba ti wọn n gbe lawọn ilẹ okeere kaakiri agbaye lori ẹrọ ayelujara.
O ni bo tilẹ jẹ pe ko si kinni kan bayii to le di gomina yii ati Aṣiwaju Bọla Tinubu lọwọ lati ri Aarẹ Muhammadu Buhari, sibẹ, niṣe ni wọn n ba ojuṣaaju kiri, ti iya buruku si n jẹ awọn eeyan wọn nilẹ Yoruba.
Oloye Sunday Adeyẹmọ sọ pe, “Pupọ ninu awọn aṣaaju ta a ni nilẹ Yoruba ni wọn n sa kiri, ti wọn ko sọ ootọ ọrọ fun Aarẹ Buhari nipa wahala tawọn Fulani n da silẹ nilẹ Yoruba nitori ipo ti wọn n wa nidii oṣelu.”
Igboho fi kun un pe pupọ ninu awọn oloṣelu ilẹ Yoruba ni wọn maa n sọ nnkan mi-in ti wọn ba ti de ilu Abuja, ati pe asiko ti a wa yii, oun ṣetan lati koju ẹnikẹni to ba kẹyin si iran Yoruba lori wahala tawọn janduku Fulani n ko n ko ba awọn eeyan oun.
Ṣiwaju si i, Igboho ni, “O ṣe ni laaanu pe awọn oloṣẹlu ta a ni yii ko ni anfaani kankan ti wọn fẹẹ ṣe fun iran Yoruba, awọn Bọla Tinubu atawọn eeyan ẹ ti di ẹru Fulani, ko si anfaani kan bayii ti wọn le ṣe fun iran Yoruba, awa ni ki a ja funra wa. Ẹyin naa ẹ wo Ṣeyi Makinde ta a dibo fun, ta a ro pe yoo ṣe daadaa, bi yoo ṣe pada wa lẹẹkan si i lo n ba kiri, ti iya buruku si n jẹ iran Yoruba lọwọ Fulani. Eti Ṣeyi Makinde ti di patapata si ariwo ti awọn eeyan ẹ n pa, asiko niyi lati ja fun iran wa, ki a le bọ patapata.”