Faith Adebọla
Gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ti kede pe nibi tọrọ aabo to mẹhẹ lorileede yii de duro bayii, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde yii, oun atawọn eeyan oun yoo bẹrẹ si i wọgbo lọọ ba awọn janduku agbebọn, awọn ajinigbe atawọn Fulani darandaran nibikibi ti wọn ba sa pamọ si.
Ninu fidio kan to fi lede, nibi ti amugbalẹgbẹẹ ati agbẹnusọrọ rẹ, Ọgbẹni Ọlayọmi Koiki, ti fọrọ wa a lẹnu wo, Sunday Igboho ni asiko ti to wayi lati da iwa ọdaran awọn Fulani agbebọnrin duro nilẹ Yoruba.
O ni, “Awọn eeyan ni ki n ma sọrọ pupọ mọ ni mo fi dakẹ tẹlẹ, ki i ṣe ti ojo. Ṣugbọn ni bayii, emi funra mi gan-an ni mo maa wọgbo lọọ ba awọn Fulani atawọn janduku agbebọn lati ọjọ Mọnde yii lọ. Iṣẹ ti bẹrẹ bayii. Ko sọrọ bandiiti (bandits) mọ, ko si pe ẹnikan n gbegi dina, tabi jiiyan gbe mọ.
Ọkunrin naa leri pe gbogbo nnkan ija awọn agbebọn naa lawọn maa gba lọwọ wọn tabi kawọn sọ ọ di otubantẹ mọ wọn lọwọ.
“Gbogbo inu igbo ilẹ Yoruba la maa fẹ atẹgun si, gbogbo ibi tawọn kọlọransi naa ba wa ni wọn ti maa jade wa, a maa jẹwọ Yoruba fun wọn.”