Sunday to n pawọn eeyan l’Akinyẹle ti jẹwọ o: Eyi ni bi mo ṣe sa mawọn ọlọpaa lọwọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbajugbaja afurasi ọdaran to wa loju ọpọn bayii, Sunday Shodipẹ, ẹni ti gbogbo aye mọ gẹgẹ bii ẹni to n pa awọn eeyan nipakupa nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan, ti ṣalaye ọna to gba sa lọ mọ awọn ọlọpaa lọwọ ninu ahamọ ti wọn fi i pamọ si.

Sunday, ọmọọdun ọdun mọkandinlogun yii, lo fẹnu ara ̣ẹ jẹwọ pe oun loun pa awọn eeyan ti wọn pa nipakupa lagbegbe Akinyẹle, n’Ibadan, ati pe ṣọ́bìrì loun fi maa n ṣa wọn lori titi ti wọn yoo fi japoro lọ sọrun aremabọ.

Ninu oṣu keje, ọdun 2020 yii, lọwọ awọn agbofinro kọkọ tẹ ẹ, ti ile-ẹjọ si paṣẹ pe ki wọn tọju ẹ sinu ahamọ wọn nigba ti wọn pe e lẹjọ ipaniyan si kootu Majisireeti n’Ibadan.

Ṣugbọn lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja, lafurasi ọdaran yii sa kuro latimọle.

Ọpọ araalu niṣẹlẹ yii ru loju, afi nigba ti Sunday funra rẹ ṣalaye bo ṣe rin in fawọn ọlọpaa to n fọrọ wa a lẹnu wo n’Ibadan lẹyin tọwọ wọn tẹ ẹ pada laaạrọ ọjọ Aiku, ọsẹ yii.

Adugbo Bodija, n’Ibadan, ni wọn ti ri i mu ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ gẹgẹ bi Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, ṣe fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa.

Nigba to n jẹwọ bo ṣe sa jade kuro latimọle awọn ọlọpaa, ọmọkunrin eni ọdun mọkandinogun yii sọ pe nigba ti ọkan ninu ọlọpaa to wa ni teṣan lasiko naa fun oun lanfaani lati lọọ wẹ loun sa mọ wọn lọwọ.

O ṣalaye pe “Nigba ti obinrin DPO ti wọn ṣẹṣẹ gbe de teṣan yẹn sọ fun ọlọpaa to n jẹ Funṣọ pe ki wọn jẹ ki n wẹ ni mo gun ori tanki omi lọ, ti mo si gbabẹ bẹ si odi keji fẹnsi lasiko ti mo ri i pe Funṣọ n ba ẹnikan sọrọ lọwọ, ti ko si fọkan sọdọ temi mọ.

“Awọn to n gbe adugbo yẹn ri mi nigba ti mo fo fẹnsi jade, ṣugbọn wọn ko sọ nnkan kan.”

Sisa ti ogboju afurasi apaayan yii sa kuro lahaamọ awọn agbofinro lo mu ki ọga agba ọlọpaa nilẹ yii, IGP Muhammed Adamu, sare fi ikọ awọn ọlọpaa to nimọ ijinlẹ nipa bi wọn ṣe n wa ọdaran to ba fara sin ranṣẹ si ipinlẹ Ọyọ lati wa ọmọkunrin afurasi ọdaran naa jade kia, ti ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu, si tun kede ẹbun ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) fun ẹnikẹni to ba le ran awọn ọlọpaa lọwọ lati ri ri ẹruuku naa mu pada.

Riri ti wọn pada ri Sunday mu lọjọ Aiku lo fi ọkan awọn olugbe ijọba ibilẹ Akinyẹle balẹ, ti awọn adari agbegbe naa si gboṣuba fun awọn agbofinro fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati ri i pe ọrọ naa ri bi wọn ṣe fẹ.

Wọn ni latigba ti awọn ti gbọ pe ọmọkunrin naa sa jade latimọle lọkan awọn nitori awọn ko mọ igba ti jagunlabi yoo tun pada wa sagbegbe awọn lati tun bẹrẹ si i maa paayan gẹgẹ bii iṣe ẹ.

Lara awọn adari ijọba ibilẹ kinyẹle to fi idunnu wọn han si aṣeyọri awọn ọlọpaa yii ni Oniroko tilu Iroko, Ọba Ọlasunkanmi Abioye Ọpẹọla, Baalẹ Amusa Akinade Ajani ti i ṣe Baalẹ Ṣaṣa ati Ọnarebu ati Ọnarebu Taoreed Jimoh ti ṣe alaga afunṣọ ijọba ibilẹ Akinyẹle.

3 thoughts on “Sunday to n pawọn eeyan l’Akinyẹle ti jẹwọ o: Eyi ni bi mo ṣe sa mawọn ọlọpaa lọwọ n’Ibadan

Leave a Reply