Tẹgbọn-taburo dero ẹwọn, igbo ni wọn ka mọ wọn lọwọ n’Ileefẹ  

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣebi ọmọ-iya meji ki i ṣe owo aipe lawọn agbalagba maa n wi, ọrọ ko ri bẹẹ fun Fẹmi Abiọla ati aburo rẹ, Tọpẹ Abiọla, ọmọ ẹgbẹ okunkun hanranhun lawọn mejeeji, bẹẹ ni igbo mimu ko jẹ nnkan kan fun wọn. Ọmọ ọgbọn ọdun ni Fẹmi, aburo rẹ si jẹ ọmọ ọdun mejidinlọgbọn, wọn tun ni ọrẹ kan ti wọn jọ n huwa buruku naa, Stephen James, to jẹ ọmọ ọdun mejidinlọgbọn ni tiẹ, awọn mẹtẹẹta si lọwọ awọn ọlọpaa tẹ.

Agbefọba to jẹ olupẹjọ, Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi, sọ ni kootu pe aago mẹfa kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn irọlẹ ọjọ karun-un, oṣu keje, ọdun yii, lawọn mẹtẹẹta huwa ọhun lagbegbe Ọranmiyan, Atiba ati London Street, niluu Ileefẹ.

Ọsanyintuyi ṣalaye pe ọmọ ẹgbẹ okunkun torukọ rẹ n jẹ Aye Confraternity lawọn mẹtẹẹta, wọn si ti sọ ara wọn di ẹrujẹjẹ fun awọn olugbe agbegbe ọhun.

Yatọ si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, Ọsanyintuyi sọ pe awọn ọlọpaa tun ka igbo (indian hemp) to to kilogiraamu marun-un ti wọn n mu mọ wọn lọwọ lọjọ naa.

Pẹlu ẹsun mejeeji yii, Ọsanyinruti sọ pe awọn mẹtẹẹta tọ si ijiya labẹ ipin kẹta, ikẹrin, ikejilọgọta ati ikẹtalelọgọta abala ofin aadọrin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.

Agbẹjọro wọn, Comfort Eyiolawi, bẹ kootu lati faaye beeli silẹ fun wọn lai mu inira lọwọ rara, pẹlu ileri pe wọn yoo fi awọn oniduuro to ṣe e fọkan tan silẹ.

Adajọ A. A. Adebayọ fun awọn mẹtẹẹta ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-un naira ati  oniduro kọọkan ni iye kan naa.

Adebayọ fi kun idajọ rẹ pe awọn oniduuro naa gbọdọ wa ni ipele owo-oṣu kẹjọ lẹnu iṣẹ ijọba, ki agbefọba si mọ adirẹsi ile ti wọn n gbe daadaa. Ṣugbọn o ni ki wọn kọkọ lọọ fi awọn mẹtẹẹta pamọ sọgba ẹwọn titi digba ti agbẹjọro wọn yoo ri ọna abayọ lori awọn oniduuro ti wọn fẹẹ lo.

Leave a Reply