Adefunkẹ Adebiyi
Titi dasiko yii ni ojo epe ṣi n rọ lori ọkunrin ti ẹ n wo fọto rẹ yii, idi ni pe ko sẹni to gbọ pe niṣe lo ji akẹkọọ ti ko ju ọmọ ọdun marun-un lọ gbe, to si tun waa fun un ni majele jẹ nigba to ri i pe ọmọdebinrin naa da oun mọ daadaa.
Abdulmalik Mohammed lọkunrin yii n jẹ, tiṣa ti wọn da gba fun Hanifa Abubakar, ọmọ ọdun marun-un to ji gbe ni. Afi bi tiṣa yii ṣe bẹ ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Hashim Isyaku lọwẹ, ti wọn jọ ji ọmọdebinrin yii gbe lọjọ keji, oṣu kejila, ọdun 2021.
Bi wọn ṣe ji i gbe, miliọnu mẹfa naira ni wọn beere fun, ti wọn ni kawọn obi ọmọ naa waa sanwo ọhun kia bi wọn ba fẹẹ ri ọmọ wọn pada.
Lasiko ti wọn fi ji Hanifa gbe yii, ti awọn eeyan n lọ sile wọn ti wọn n ba wọn daro, tiṣa to ji i gbe yii ni wọn lo kọkọ dele wọn, to n sunkun kikoro bo ṣe n ba wọn daro, bẹẹ ni wọn lo n ṣadua pe Allah yoo ṣe ọmọ naa ni riri o, bẹẹ, oun lo tọju rẹ sibi kan to n reti owo itusilẹ.
Nigba tọmọ to ji gbe yii fi wa lahaamọ rẹ ni tiṣa ẹni ọgbọn ọdun naa woye pe ọmọ yii da oun mọ, o mọ pe bawọn obi rẹ ba sanwo ọhun tan, yoo sọ fun wọn pe oun loun wa nidii ijinigbe naa, aṣiri yoo si tu, iyẹn lo fi fi majele sounjẹ fọmọdebinrin naa, to si pa a.
Inu ọgba ileewe aladaani kan to wa ni Kwanar Yan Gana, Tudun Murtala Quarters, ni Kano, ni wọn lọọ sinku Hanifa si. Ki i ṣe pe wọn sin oku naa lodidi, niṣe ni wọn kun un bii ẹran ki wọn too sin si koto ti ko jin.
Nigba ti wọn ti ji Hanifa gbe lawọn obi rẹ ti fi to ọlọpaa leti, iwadii to jinlẹ ni wọn si fi mọ pe Abdulmalik Mohammed ati Hashim Isyaku lo wa nidii ijinigbe ati iku ọmọ naa.
SP Abdullahi Haruna Kiyawa,Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kano, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ l’Ọjọbọ to kọja yii.
O ni lọjọ kẹrin, oṣu kejila, ọdun 2021, ni ifisun kan de sọdọ awọn ọlọpaa, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ. O ni Dakata Quarters, Kano, lẹni to mu ẹsun naa wa ti wa, ohun to si sọ ni pe Hanifa Abubakar ti ko ju ọmọ ọdun marun-un lọ ti di awati, wọn ti ji i gbe lọ.
Ọlọpaa yii ni bẹẹ ni Operation Puff Adder bẹrẹ iṣẹ pẹlu awọn ikọ alaabo mi-in atawọn ọtẹlẹmuyẹ DSS, nigbẹyin lọwọ ba Abdulmalik Mohammed; ẹni ọgbọn ọdun, ati Hashim Isyaku, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji( 37).
Afurasi keji, Hashim, jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ninu oṣu kọkanla, ọdun 2021, ni tiṣa to ji akẹkọọ ẹ gbe yii ti kọkọ pe oun fun iṣẹ ijinigbe naa.
O ni Abdulmalik ati obinrin kan, Fatima Musa, ni wọn ni koun bawọn ji Hanifa gbe nigba naa. O ni gbogbo eto ti yoo jẹ ko ṣee ṣe ni wọn ti lana ẹ silẹ, ṣugbọn nigba to tun ya ni wọn tun pa ero naa ti, koun ati Abdulmalik too waa jọ ṣe ni Disẹmba to kọja yii.
Bo ṣe jẹwọ yii lawọn ọlọpaa ti wa Fatimọ Musa to darukọ naa kan, oun naa si ti wa lahaamọ gẹgẹ bii awọn meji yooku.
Awọn afurasi yii mu awọn ọlọpaa lọ sibi ti wọn sin oku Hanifa si, wọn hu eyi to ku, wọn ṣayẹwo si i, wọn si yọnda ẹ fawọn eeyan ẹ lati lọọ sin in.
Laipẹ yii ni wọn yoo ko wọn lọ si kootu gẹgẹ bii Alukoro ọlọpaa Kano ṣe wi. Ṣugbọn ki idajọ too de, awọn eeyan ti gbe eto kan dide lori ayelujara, ‘Justice for Hanifa’ ni wọn pe e, iyẹn ni pe wọn n beere idajọ ododo fun ọmọ ọlọmọ ti wọn ṣẹ lori lojiji yii, bẹẹ lawọn mi-in n ṣepe rabandẹ fun tiṣa to ji akẹkọọ ẹ gbe, to tun lọwọ ninu iku ọmọ ọlọmọ.