Ti ẹ ba ni kawọn Fulani ma fi maaluu jẹko ni gbangba mọ, ẹ ni lati wa ọna miiran fun wọn-Gomina Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti sọ pe ipenija eto aabo ni ẹkun Ariwa orile-ede Naijiria, paapaa ju lọ bawọn gomina ni Guusu orile-ede yii ṣe kede ifofin de ifẹran jẹko ni gbangba, o ti mu ki awọn Fulani darandaran maa ya wọ ipinlẹ Kwara kẹtikẹti, ti ko si rọrun lati gbe ofin ma- fẹran-jẹko kalẹ.

Nibi ifọrọwanilẹnu wo ti wọn ṣe fun Gomina Abdulrazak lo ti fọrọ naa lede fun awọn oniroyin, o ni awọn ajeji Fulani darandaran to n ya wọ Kwara ti n pọ ju awọn ọmọ onile lọ bayii. Abdulrasaq ni ti ba wo Guusu ipinlẹ Kwara, ti a si de Ariwa ipinlẹ Kwara, atawọn abule miiran, a o ri i pe, ṣe ni awọn Fulani darandaran ọhun n wọ ibẹ kẹtikẹti, ti wọn si ti fẹẹ pọ ju awọn ọmọ ilu lọ.

Gomina ni ofin ma-fẹran-jẹko ko ṣe e fagbara mu, tori pe ọrọ ẹtọ ọmọniyan ni, ọmọniyan le rin yan fanda bo ṣe wu u, idi ni pe o ti wa ninu iwe ofin orile-ede Naijiria. O ni ti ẹ ba ri awọn ọmọ Fulani ninu igbo, wọn o kawe, lẹyin ki wọn maa da maaluu kiri ninu igbo, awọn agbẹ n ya owo ti wọn fi n dako, awọn Fulani n fi maaluu jẹ ẹ, ti wọn si ri inu oko gẹgẹ bii ọna fun awọn maaluu wọn. Gomina beere pe oju ọna ti awọn oyinbo amunisin ṣe fawọn Fulani darandaran lọjọsi da? Awọn oyinbo ṣe ọna ọhun fun wọn, ti wọn si fi awọn ẹṣọ sibẹ ti wọn n gbowo ori lọwọ wọn, sugbọn ni bayii, gbogbo ọna naa ni awọn agbẹ fi n dako, nibo ni ki awọn Fulani maa ko maaluu wọn gba.

O tẹsiwaju pe bi ilu ṣe n tobi ti awọn eeyan n kọle, ti wọn n gba iwe ilẹ wọn, tumọ si pe wọn ti n lo ilẹ to yẹ ki awọn maaluu maa gba niyẹn. Ọmọ Naijiria ni wọn, wọn si lẹtọ lati rin lori ilẹ bo ṣe wu wọn labẹ ofin, ti ẹ ba si ni wọn o gbọdọ fi maaluu jẹko ni gbangba mọ, ẹ ni lati wa ọna miiran fun wọn.

Gomina Abdulrazak ni awọn yoo gbe igbimọ kalẹ ti yoo wa ọna abayọ si ipenija yii, ti wọn yoo sọ fun awọn to ni ilẹ ko fun awọn Fulani darandaran ni ilẹ, o ni koda, ki wọn fun wọn ni ilẹ, iṣoro yoo tun wa pẹlu tori pe ijọba ipinlẹ ko ni ilẹ, bi ijọba ba gba ilẹ awọn kan, wọn gbọdọ san owo ‘gba ma binu’ fun awọn to ni ilẹ naa, eyi lo mu ki awọn gomina kan maa beere owo lọwọ ijọba apapọ fun eto naa, tori pe ijọba ipinlẹ nilo lati ra ilẹ.

Abdulrazaq sọ pe wọn gbọdọ mu idaduro ba ofin ma-fẹran-jẹko, ninu ki wọn fun awọn lowo ‘gba-ma binu’ tabi ki wọn fun wọn lasiko diẹ ki wọn le wa ọna abayọ si iṣoro ‘ma-fẹran-jẹko’ ni gbangba, tori pe bayii, awọn Fulani n ra ounjẹ fun awọn maaluu wọn ni, eyi to mu ki ẹran maaluu wọn lori atẹ.

Leave a Reply